Lẹyin ipade pẹlu aṣoju ijọba Eko, awọn olugbe Lẹkki lawọn ko sanwo too-geeti kankan mọ o

Jọkẹ Amọri
Lẹyin ti wọn dide nibi ipade pataki kan ti wọn ṣe ni Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, ẹgbẹ awọn olugbe ilu Lẹkki, nipinlẹ Eko, ti fohun ṣọkan pe awọn ko ṣetan lati san owo too-geeti ti ileeṣẹ to n mojuto awọn oju ọna naa, LCC, lawọn fẹẹ bẹrẹ si i gba pada lati ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹrin, yii.
Gbajugbaja adẹrin-poṣonu ilẹ wa nni, Adebọwale Adedayọ ti gbogbo eeyan mọ si Mr Macaroni, lo fi eleyii lede lori ikanni abẹyẹfo (twitter), rẹ.
O kọ sibẹ pe, ‘‘A wa nibi ipade pẹlu awọn ileeṣẹ to n mojuto too-geeti Lẹkki ati ẹgbẹ awọn olugbe ilu naa. Nibi ipade yii ni alaga ẹgbẹ ọhun ti wọn pe ni ‘‘The Lekki Estate Residents and Stakeholders Association (LERSA) ti kede pe awọn ko fara mọ owo too-geeti ti wọn ni wọn tun fẹẹ maa gba pada, awọn ko si ṣetan lati san an.
Nigba to n ba ALAROYE sọrọ nipa ipade naa, Adedayọ sọ pe oun naa wa nibi ipade ọhun gẹgẹ bii olugbe adugbo naa. O ni oun lọ sibẹ lati mọ bi gbogbo ipade naa ṣe lọ, ati pe nitori pe ọrọ naa kan oun gẹgẹ bii olugbe adugbo Lẹkki loun ṣe yọju sibẹ. Bakan naa lo ni awọn oṣere mi-in bii Fọlarin Falana ti gbogbo eeyan mọ si Fals, Banky W., Dele Farotimi, awọn alaga oriṣiiriṣii ẹgbẹ, to fi mọ awọn ti wọn n gbe ni agbegbe 1004 si ọna Epẹ, ni wọn wa nibi ipade ọhun.
Maccaroni ni kọmiṣanna fun eto iroyin, ti eto irinna ati ọrọ to n lọ labẹle pẹlu ọga agba ileesẹ to n ri si too-geeti Lẹkki (LCC), ni wọn peju sibi ipadeyii.
Ohun ti wọn si sọ ni pe awọn wa lati fikunlukun pẹlu awọn olugbe agbegbe naa lori erongba awọn lati ṣi too-geeti naa pada. Ṣugbọn pẹlu bi awọn eeyan naa ko ṣe fara mọ ipinnu yii, ti wọn ni ko si ohun to jọ ọ, awọn eeyan ijọba yii ni awọn yoo fi ipinnu wọn yii to ijọba ipinlẹ Eko leti, awọn yoo si pada fun wọn labọ ohun ti awọn ba fẹnu ko si.
Tẹ o ba gbagbe, aipẹ yii ni ileeṣẹ naa kede pe awọn fẹẹ ṣi too-geeti yii pada lọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹrin, nibi ti wọn ti fun awọn eeyan naa lanfaani lati lo oju ọna ọhun lọfeẹ fun ọjọ mẹẹẹdogun, ti wọn si ni lẹyin ọjọ mẹẹẹdogun lawọn yoo too bẹrẹ si i gbowo lọwọ awọn olugbe agbegbe naa to ba n ṣe amulo ọna yii.

Leave a Reply