Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Lati ọjọ kejileogun, oṣu kẹrin, ọdun 2020, ti ọmọbinrin kan, Favour Okon, ọmọ ọdun mẹtadinlogun, ti ṣagbako ibasun lọwọ Godday Robinson, gende ẹni ọdun mejidinlọgbọn to fipa ba a lo pọ lagbegbe OPIC, Agbara, nijọba ibilẹ Ado-Odo, ni ko ti si alaafia fun un mọ. Ọsibitu lo wa lati ọjọ naa, Ọjọbọ to kọja yii si ni Favour ṣiwọ iṣẹ, to ku patapata.
Bi ẹ ko ba gbagbe iṣẹlẹ yii, aarọ kutu ni Favour n bọ lati ibi iṣẹ alẹ to lọ lọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹrin, aṣe Robinson to ti ni ko jẹ kawọn maa fẹra awọn, ti ọmọ naa ko gba, ti lọọ dena de e. Niṣe lo si fa Favour wọnu igbo, to lu u bii ko ku ko too fipa ba a lo pọ.
Lẹyin ibalopọ naa lo fun ọmọge yii lọrun, to si ti i sinu ọgbun kan to wa nitosi, lo ba ba tiẹ lọ, o ro pe ọmọge naa ti ku ni.
Ṣugbọn Favour ko ku nigba naa, o ji pada ninu koto ti Robinson ju u si, o si n kegbajare pe kawọn eeyan ran oun lọwọ. Awọn ẹlẹyinju aanu to n kọja lọ lo gbe e lọ sọsibitu akọkọ, lati ibẹ ni wọn ti gbe e wa si FMC, l’Abẹokuta.
Ninu itọju FMC ni wọn ti mọ pe egungun ẹyin (spinal cord) ọmọbinrin yii ti kan latari koto ti afipabanilopọ naa ti i si, n lo ba tun di pe wọn gbe e lọ si ọsibitu elegungun to wa ni Igbobi, l’Ekoo, nibi to ti gba itọju titi, ṣugbọn ti iku pa oju rẹ de l’Ọjọbọ to kọja yii.
Ijọba ipinlẹ Ogun lo ti n ṣeto inawo ọsibitu Favour lati igba ti ọrọ rẹ ti ṣẹlẹ, nigba to si pada ja si iku yii, ijọba tun ran Kọmiṣanna fọrọ awọn obinrin, Olufunmilayọ Ẹfuwapẹ, lati ṣoju ipinlẹ Ogun, bi wọn ṣe ṣeto isinku ọmọdebinrin ti wọn bi lọdun 2003 naa si itẹ oku to wa nitosi Buhari Estate, l’Abẹokuta niyi.
Ninu ọrọ kọmiṣanna lọjọ naa, o fi ọkan awọn eeyan Favour balẹ, o ni wọn yoo ri idajọ ododo gba lori Robinson to fibasun pa wọn lọmọ.
Ṣe ṣaaju ni Kọmandi ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti foju ọkunrin naa han ni Eleweeran gẹgẹ bii afipabanilopọ ati ẹni to gbiyanju lati paayan. Ṣugbọn ni bayii ti ọmọ to fipa ba ṣere ifẹ ti jẹ Ọlọrun nipe, ẹjọ Robinson naa ti yipada kuro ni ti igbiyanju lati paayan lasan, o ti di ti apaayan pọnbele, yoo si jẹjọ ifipabanilopọ pẹlu.