Monisọla Saka
Ko jọ pe ọmọkunrin afurasi ole tẹ ẹ n wo ninu aworan yii, Chinedu Ike, ẹni ọdun marundinlọgbọn (25),lọrọọ gbọ o. Lẹyin oṣu meji to lọọ jale lagbegbe Iyana Oworo, nipinlẹ Eko, tawọn ero to wa nibẹ lu u titi ti ko fi ri apa tabi ẹsẹ gbe mọ, ti wọn si fẹẹ dana sun un, ṣugbọn to jẹ awọn ikọ ọlọpaa ayarabiaṣa (RRS ), to de sasiko lo gba a silẹ lọwo awọn ti wọn fẹẹ pa a, ti wọn sare gbe e digbadigba lọ sileewosan lo tun lọọ jale mi-in, tọwọ si pada tẹ ẹ.
Lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun yii, lo tun ṣe bo ṣe maa n ṣe, inu mọto kan ti wọn paaki kalẹ lo yọ lọ sinu rẹ, o si ji foonu ẹni to ni ọkọ naa gbe lagbegbe Iyana Oworo kan naa, nipinlẹ Eko.
Awọn eeyan ti wọn mọ Chinedu daadaa ni wọn ri i to n rin gberegbere lagbegbe naa, ni wọn ba tẹ onimọto ọhun lẹsẹ mọlẹ pe ko tete fura o, ọmọkunrin ole naa ti wa nitosi.
Afi bi ọkunrin naa ṣe ri i pe foonu oun ti poora ninu mọto to fi si. Inu baagi Chinedu lawọn oṣiṣẹ RRS ti ri foonu Infinix Note 10, to jẹ ti ọkunrin onimọto ọhun.
Awọn ikọ ọlọpaa RRS ti wọn doola ẹ lọjọsi naa ni wọn pada fi panpẹ ofin gbe e. Lẹyin ọpọlọpọ iwadii nigba to de agọ ọlọpaa, o jẹwọ pe loootọ loun ṣiṣẹ buruku naa, wọn si ti foju rẹ ba kootu.