Adeoye Adewale
‘’Ki i ṣẹ dandan rara lati nifẹẹ ọkọ mi, Ọlọrun Ọba si ṣe e, mi o ti i loyun tabi bimọ kankan fun un, oṣu mẹrin pere naa la fi fẹra wa sile, mo si ti ṣetan bayii lati san ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un Naira ti ọkọ mi san gẹgẹ bii owo-ori mi pada fun-un bayii. Ohun ti mo n fẹ ni pe ki adajọ ile-ẹjọ yii tu wa ka ni kia, ṣebi o wa ninu ofin ẹsin Islam paapaa pe iyawo le kọ ọkọ re silẹ ti ko ba sifẹẹ kankan mọ laarin awọn mejeeji, eyi ti wọn n pe ni ‘ Khul’, ofin ati igbesẹ ọhun ni emi paapaa fẹẹ tọ bayii, mi o ṣe mọ o, Oluwa mi, ẹ tu wa ka loju-ẹsẹ.’
Eyi lọrọ to n jade lẹnu iyaale ile kan, Abilekọ Sumayya Muhammad, ẹni ọdun mọkandinlogun, to gbe ẹjọ ọkọ rẹ lọ si ‘Sharia Court’, to wa lagbegbe Magajin Gari, nipinlẹ Kaduna, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ keje, oṣu Keje, ọdun 2023 yii.
ALAROYE gbọ pe igbeyawo ti ilana ẹsin Musulumi kan ti wọn n pe ni ‘Nikkah’ ni awọn ololufẹ mejeeji yii ṣe, ati pe igbeyawo ti Sumayya ni ki wọn tu ka yii ko ti i ju bii oṣu mẹrin pere lọ.
Ninu ọrọ Lọọya I.T Sanusi, to n ṣoju Sumayya nile-ẹjọ naa lo ti sọ pe onibaara oun ṣetan bayii lati san ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un Naira pada fọkọ rẹ gẹgẹ bii owo-ori to san fawọn obi rẹ lakooko ti wọn ṣegbeyawo wọn.
Sumayya ni ki ile-ẹjọ naa b’oun gba ẹgbẹrun mẹwaa Naira ti ọkọ oun jẹ oun ko too di pe wọn tu awọn mejeeji ka.
Iyaale ile yii ni, ‘Mi o ro pe mo nifẹẹ ọkọ mi yii mọ rara, afi bii ẹni pe wọn fi nnkan bo mi loju ki n too fẹ ẹ ni.’
Ninu ọrọ tiẹ, ọkọ Sumayya ni ẹgbẹrun mẹsan-an aabọ Naira loun jẹ iyawo oun, ki i ṣe ẹgbẹrun mẹwaa Naira gẹgẹ bi ohun to sọ nile-ẹjọ. O ni ki adajọ ṣi ṣe suuru fawọn mejeeji lati lọ sile, boya awọn le ri ọrọ ọhun yanju laarin ara awọn ko too di pe wọn tu awọn ka.
Loju-ẹṣẹ ti ọkọ Sumayya ti sọro yii ni Onidaajọ Malam Rilwanu Kyaudai, ti sun igbẹjọ awọn mejeeji siwaju, to si rọ Sumayya pe ko faaye gba ki atunṣe waye laarin awọn mejeeji ko too dọjọ ti igbẹjọ yoo tun waye lori ọrọ wọn.