Faith Adebọla
Lẹyin ọdun kan aabọ ti wọn ti ti too geeti Lẹkki pa, awọn alaṣẹ ileeṣẹ naa ti fi ipinnu wọn lati ṣi i pada lọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹrin, ọdun yii. Wọn ni ileeṣẹ naa ko ni i gba owo oju ọna yii fun odidi ọsẹ meji lẹyin tawọn ba ṣi i tan. Odidi ọjọ mẹẹẹdogun lawọn to ba n gba oju ọna naa yoo fi gba a lọfẹẹ lai sanwo. Ṣugbọn to ba ti di ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹrin, gbogbo ẹni to ba gba’bẹ ni yoo maa sanwo. ti awọn to ba gba oju ọna naa yoo si bẹrẹ si i sanwo pada.
Ninu ikede kan ti wọn ṣe sinu iwe iroyin, ọga agba ileeṣẹ naa, Rẹmi Ọmọmuwasan, sọ pe o ṣẹ pataki ki oju ọna naa di ṣiṣi lẹyin ti awọn ti ṣepade pẹlu awọn alẹnulọrọ gbogbo. Ninu wọn ni ijọba ipinlẹ Eko, awọn ọba alaye, ẹgbẹ awọn to n gbe agbegbe naa atawọn eeyan gbogbo tọrọ kan.
O ni oriṣiiriṣii nnkan igbalode lawọn ti ṣe agbekalẹ rẹ ti yoo mu ki oju ọna naa ṣee rin, ti yoo si ya daadaa fun awọn ti wọn ba gba a.
Tẹ o ba gbagbe, ogunjọ, oṣu Kẹwaa, ọdun to kọja ni wahala nla ṣẹlẹ ni too geeti yii lasiko ti awọn ọdọ n ṣe iwọde EndSars, ti awọn ṣọja si lọọ yinbọn pa awọn kan ninu wọn.
Ọrọ naa di wahala nla, ti wọn fi dana sun gbogbo too geeti naa.