Lẹyin ọdun meje ti wọn ti n jẹjọ ẹsun idigunjale, ọmọ iya meji gba idajọ iku l’Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

 

Ile-ẹjọ giga to wa ninu ọgba ẹwọn Olokuta, niluu Akurẹ, ti dajọ iku fun tẹgbọn-taburo kan, Isaac Sunday àti Isaac Lucky, pẹlu ẹni kẹta wọn, Ovie Nana Friday, lori jijẹbi ẹsun idigunjale ti wọn fi kan wọn.

Ọjọ kọkanla, osu kejila, ọdun 2013, ni wọn lawọn ikọ adigunjale ẹlẹni mẹta ọhun lọọ ba wọn lalejo niluu Bọlọrunduro to jẹ ibujokoo ijọba ibilẹ Ila-Oorun Ondo, ti wọn si fi ibọn atawọn nnkan ija oloro mi-in gba awọn ẹru bii foonu loriṣiiriṣii, owo ati ọkada kan lọwọ wọn.

Ko pẹ ti wọn ṣiṣẹ ibi ọhun tán tọwọ ọlọpaa fi tẹ wọn lọdun naa lọhun-un. Ibẹrẹ ọdun 2014 ni wọn kọkọ foju wọn ba ile-ẹjọ lori ẹsun mẹfa ọtọọtọ tí wọn fi kan wọn.

Awọn ẹsun ọhun ni agbẹjọro ijọba, Olusẹgun Akeredolu, ni o lòdì, tó sì tun ni ijiya to lagbara labẹ ofin orilẹ-ede yii ti ọdun 2004, eyi to ta ko iwa idigunjale ati ṣiṣe amulo nnkan ija oloro lai bofin mu.

Awọn elẹrii mẹrin ni agbefọba ọhun pe lati jẹrii ta ko awọn ọdaran ọhun pẹlu iwe ti wọn kọ ní tesan, nibi ti wọn ti jẹwọ pe loootọ lawọn huwa ibi naa.

Lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja, ni Onidaajọ Yẹmi Fasanmi sọ pe olupẹjọ ti gbiyanju ati fidi ẹjọ rẹ mulẹ pe loootọ lawọn ọdaran mẹtẹẹta jẹbi gbogbo ẹsun ti wọn fi kan wọn.

Adajọ ni oun pasẹ kí wọn lọọ yẹgi fun wọn titi ti ẹmi yoo fi bọ lara wọn.

 

Leave a Reply