Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta
Gẹgẹ bi akọsilẹ kootu ṣe wi, ọjọ kẹẹẹdogun oṣu kẹsan-an ọdun 2013 ni ọkunrin kan ti wọn ni fijilante loun naa, Sheu Jimọh, yinbọn pa ẹnikan ti wọn pe orukọ ẹ ni Tosin Joye, ni Mowe. Ṣugbọn lọjọ Ẹti ti kọja yii, eyi ti i ṣe ọdun kẹjọ lẹyin iṣẹlẹ naa,kootu giga ilu Abẹokuta dajọ iku fun Sheu,wọn ni ki wọn yẹgi mọ ọn lọrun titi ti yoo fi ku.
Adajọ Abiọdun Akinyẹmi lo gbe idajọ naa kalẹ pẹlu alaye pe awijare kan ko si lori keesi yii mọ, gbogbo ẹ lo foju han pe Sheu yinbọn paayan, oun naa si gbọdọ ku gẹgẹ bi ofin ṣe wi ni.
Obinrin ni agbefọba lori ẹsun yii, orukọ rẹ ni Abilekọ Oluwaṣeni Ogunjimi. Obinrin yii ṣalaye pe ni nnkan bii aago mẹsan-an alẹ ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kẹsan-an ọdun 2013 ni Sheu to jẹ ọkan lara awọn fijilante igba naa , yinbọn pa Tosin Joye, ni ikorita Atala, lagbegbe Bọlatito, Mowe.
O fi kun un pe Tosin pẹlu awọn ọrẹ ẹ fẹẹ lọọ ra omi inu ọra ti wọn n pe ni piọ wọta ni. Afi bi fijilante yii ṣe yinbọn mọ wọn laiṣẹ,Tosin ni ibọn ọhun ba ninu gbogbo awọn ti wọn n lọ naa, nibi ti wọn si ti n gbe e lọ sileewosan lo ti dakẹ loju ọna, to ku patapata.
Ẹnu ẹjọ yii ni wọn wa latigba naa, ko too di pe Adajọ Abiọdun Akinyẹmi da a lọjọ Ẹti to kọja yii, pe ki wọn yẹgi mọ Sheu lọrun, koun naa maa lọ sibi to ran Tosin Joye lọ.