Lẹyin ọdun mẹrin to ti wa nipo adele, Ọmọọba Agbọna ti kuro lori oye

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Adele-ọba ti ilu Aye, n’ijọba ibilẹ Ifẹdọrẹ, Ọmọọba Taiwo Oyebọla Agbona, ti kuro lori oye lẹyin bii ọdun mẹrin gbako to ti wa lori aleefa.

Adele-ọba tẹlẹ ri ọhun lo ṣe ikede yii fawọn eeyan lori Fesibuuku rẹ lopin ọsẹ to kọja.

Eyi lawọn ọrọ iwuri ti Ọmọọba Taiwo fi sita lati fi mọ riri awọn eeyan to duro ti i laarin ọdun mẹrin to fi wa lori itẹ awọn baba nla rẹ :

Lẹyin ti baba mi, Ọba J. B. Agbona, papoda lọ sinu ogo ni wọn yan mi gẹgẹ bii asaaju awọn eeyan mi titi di igba ti wọn yoo fi fi ọba mi-in jẹ. Mo gori itẹ Adele-ọba lọdun-un 2018, ni ibẹrẹ irinajo naa, eyi to n wa sopin bayii, ṣe lo kọkọ da bii ẹni pe ẹru gbogbo aye ni mo fẹẹ gbe le ejika, niwọn igba ti n ko figba kan mura silẹ fun iru iṣẹ nla bẹẹ tẹlẹ.

Ko si awawi mọ, ṣe a ki i wọnu odo tan ka tun ṣẹ̀ṣẹ̀ waa maa kigbe otutu, mo gba kamu, mo si pinnu ati sa gbogbo ipa mi laarin asiko ti mo ba fi wa lori oye naa.

Pẹlu iranlọwọ Ọlọrun, ọpọlọpọ awọn nnkan idagbasoke lo wọ ilu Aye, ilu ọhun ti ko si fi bẹẹ gbajumọ tẹlẹ waa di ibi tawọn eeyan n mọ jale jako. Gbogbo eeyan ilu, onile ati alejo, ni wọn jẹ ọkan-o-jọkan anfaani lati ọwọ ijọba apapọ ati ti ipinlẹ labẹ iṣakoso mi.

Lẹyin Ọlọrun, mo tun ni lati kan saara si iya to bi mi lọmọ, iyẹn Olori A. A. Agbona, fun aduroti ati iyanju rẹ lori aṣeyọri mi, ṣe ni mama mi pa awọn ilepa kan to wa niwaju rẹ, ti to si duro ti mi gbagbaagba ninu iṣẹ takuntakun oun adura gbigba ki n le ṣe aṣeyọri.

Mo tun gbọdọ mọ riri awọn ijoye atawọn igbimọ aṣejọba ilu Aye fun atilẹyin wọn lati igba ti mo ti wa lori aleefa, mi o le sọ bi irinajo ọhun iba ti ri ti ko ba si ifọwọsowọpọ lati ọdọ wọn.

Ọmọọba Taiwo tun dupẹ lọwọ iyawo Gomina ipinlẹ Ondo, Arabinrin Betty Akeredolu, atawọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ gbogbo fun atilẹyin wọn. Lẹyin naa lo gbadura ki eto iṣakoso tuntun to ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹẹ bẹrẹ niluu Aye tu tonile talejo lara.

Leave a Reply