Ọlawale Ajao, Ibadan
Gbogbo eto lo ti to bayii lati da awọn agbabọọlu to kọkọ gbe ogo Naijiria ga nilẹ Afrika, iyẹn awọn agbabọọlu ICC, Ibadan, lọla.
Ẹgbẹ awọn akọroyin ere idaraya nipinlẹ Ọyọ (Sports Writers Association of Nigeria (SWAN), pẹlu ẹgbẹ awọn agbabọọlu ti wọn ṣawari ẹbun bọọlu wọn lasiko ti wọn wa nileewe nilẹ Afrika, iyẹn African Students Football Union (ASFU) ni wọn ṣeto idanilọla ọhun.
Lara eto ti pataki yoo waye lasiko ayẹyẹ naa ni idije bọọlu ti yoo waye laarin ẹgbẹ agbabọọlu ipinlẹ Ọyọ, iyẹn 3SC, Ibadan, pẹlu Rangers International, ti ipinlẹ Enugu, lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun 2022 yii, ni papa iṣere Lekan Salami l’Adamasingba, n’Ibadan.
Gomina ipinle Rivers, Nyesome Wike, lalejo pataki ti wọn pe sibi ariya nla ọhun, oun ni yoo si gba bọọlu iṣide ifẹsẹwọnsẹ ọhun.
Ninu ipade oniroyin to ti fidi eyi mulẹ fawọn oniroyin n’Ibadan, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, Aarẹ ẹgbẹ ASFU, Ọjọgbọn Ṣeun Ọmọtayọ, sọ pe “ohun iyanu lo jẹ pe ko ti i sẹni tabi ijọba to ranti ẹgbẹ agbabọọlu ICC, Ibadan, lati ọdun 1976 ti wọn ti ṣe orileede yii logo pẹlu bi wọn ṣe gba ife-ẹyẹ ilẹ Afrika wa s’Ibadan, eyi ti to jẹ akọkọ iru ẹ ni Naijiria ati jake-jado ilẹ Afrika.
“Gbogbo awọn agbabọọlu yii le ma si ni Naijiria bayii, ṣugbọn a maa pe gbogbo wọn pọ lati bu ọla fun wọn. Allan Hawkes, oyinbo to jẹ olukọ IICC, nigba naa paapaa n bọ lati orileede England, Ṣẹgun Ọdẹgbami ti n ba a sọrọ.
Lọdun 1976 lajọ to n ṣakoso bọọlu alafẹsẹgba nilẹ Afrika, Confederation of African Football (CAF), ṣagbekalẹ idije bọọlu gbigba laarin awọn ẹgbẹ agbaboolu kaakiri ilẹ Afrika, IICC, Ibadan, eyi to ti di Shooting Stars Sports Club (3SC) bayii, lo si kọkọ gba ife-ẹyẹ ọhun gẹgẹ bii ọkan ninu awọn ẹgbẹ agbabọọlu to ṣoju orileede Naijiria ninu idije ọhun lọdun naa lọhun-un. African Cup Winners Cup ni wọn n pe orukọ idije ọhun nigba naa dipo CAF Champions League to n jẹ bayii.
Rangers International to gba ife-ẹyẹ idije yii lọdun 1977, lọdun keji ti IICC (3SC) gba a. Iyẹn lo ṣe jẹ pe laarin ẹgbẹ agbabọọlu yii pẹlu 3SC ni ifẹsẹwọnsẹ bọọlu ọlọrẹẹsọrẹẹ yoo to waye.
Bakan naa ni wọn ṣeto ifẹsẹwọnsẹ mi-in laarin gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, atawọn ọrẹ ẹ pẹlu awọn agbabọọlu to gba ife-ẹyẹ Afrika lọdun 1976, eyi ti Oloye Ṣẹgun Ọdẹgbami yoo ko sodi.
Bọ tilẹ jẹ pe ọpọ ninu awọn agbabọọlu ICC yii ni wọn ti j’Ọlọrun ni pe, gbogbo wọn, atawọn to ti ku, atawọn to ṣi wa laaye ni wọn yoo fi ami-ẹyẹ da lọla.
Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, awọn to ṣi wa laye ninu wọn ko ju mẹsan-an lọ mọ. Diẹ ara wọn ni Oloye Ṣẹgun Ọdẹgbami, Oloye Ẹmiọla Adeṣina; Sam Ashante lati orileede Ghana pẹlu Philip Boamah, ọmọ bibi orileede Ghana bakan naa, ṣugbọn to gba bọọlu fun Naijiria nigba ti ẹgbẹ agbabọọlu ilẹ yii n jẹ Green Eagles, ko too di Super Eagles to n jẹ bayii.
Lara awọn ikọ ẹgbẹ agbabọọlu ọhun ti wọn ti ku, ṣugbọn ti wọn yoo fun lami-ẹyẹ nipasẹ idile wọn ni Best Ogedegbe to jẹ aṣọle wọn, Mudasiru Lawal, Samuel Ọjẹbọde, Moses Ọtọlorin, Dauda Adepọju, Fọlọrunshọ Gambari, Adekunle Aweṣu ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Alaga ẹgbẹ awọn akọroyin ere idaraya, SWAN, nipinle Ọyọ, Ọgbẹni Niyi Alebioṣu, ti ṣapejuwe eto ami-ẹyẹ yii gege bii ẹkọ fun gbogbo eeyan, pe bi wọn ba n ṣe daadaa, bo pẹ bo ya, awọn eeyan yoo pada mọ riri wọn, aye aa si maa ranti wọn si rere.