Florence Babaṣọla
Gomina ipinlẹ Ọṣun, Alhaji Gboyega Oyetọla, ti sọ pe ki gbogbo awọn alaga ijọba ibilẹ atawọn kanselọ gbe iṣakoso agbegbe wọn le oṣiṣẹ ijọba to ga ju lọ nibẹ.
Eleyii ko ṣẹyin bi asiko to yẹ ki gbogbo awọn alaga ijọba ibilẹ ọgbọn atawọn ijọba ibilẹ agbegbe kaakiri ipinlẹ Ọṣun lo lori ipo naa ṣe wa sopin lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ karun-un, oṣu keji, ọdun 2021.
Ọdun 2018 ni wọn ṣebura fun awọn kansẹlọ ti wọn jawe olubori kaakiri awọn ijọba ibilẹ, lẹyin eyi lawọn kansẹlọ naa yan alaga atawọn oloye to ku laarin ara wọn.
Gomina Oyetọla dupẹ lọwọ gbogbo wọn fun ipa ti wọn ko ninu idagbasoke ijọba ibilẹ wọn, o si gbadura pe ki wọn ba ojurere pade ninu ohun gbogbo ti wọn ba dawọ le lọjọ iwaju.