Jọkẹ Amọri
Ọpọ awọn to gbọ ọrọ ọmọkunrin kan, Yakub Yusuf, ẹni ọdun mẹtalelogun, to tun lọọ jale lọjọ kẹta to kuro lọgba ẹwọn ni wọn n ṣọ pe ọrọ rẹ ki i ṣe oju lasan, wọn ni boya wọn ti tẹle e latile ni.
Ọwọ awọn ikọ ọlọpaa ayaraṣaṣa (RRS), lo tẹ ọmọkunrin naa laaarọ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kejila, oṣu Kọkanla yii, eroja ileeṣẹ awọn panapana lo lọọ ji gbe ninu ọgba wọn to wa ni Alausa, niluu Ikẹja.
ALAROYE gbọ pe ni ọjọ kin-in-ni, oṣu Kọkanla yii, lo lọọ jale nileeṣẹ ijọba ti wọn maa n gbe epo ti wọn ko ba lo si, (Lagos State Fuel Dump), ti wọn si mu un, ibẹ lo si gba dele-ẹjọ.
Nigba ti wọn gbe ọmọkunrin naa de kootu, adajọ ni ko san owo itanran, ti ko ba ri i san, ko lọọ ṣe ẹwọn oṣu kan. Nitori ti Yusuf ko rẹni gba beeli rẹ lẹyin idajọ ile-ẹjọ, lo mu ki wọn gbe e lọ si ọgba ẹwọn.
Ṣugbọn lọsẹ to kọja ni ẹgbẹ alaaanu kan lọ si ọgba ẹwọn ti ọmọkunrin yii wa. O jọ pe aanu wọn ṣe e nigba ti wọn ri i pe ọmọde ni. Bayii ni ẹgbẹ naa san owo itanran ti ile-ẹjọ ni ko san, iyẹn lẹyin to ti lo bii ọsẹ meji ni gbaga ninu oṣu kan ti wọn da fun un. Eyi lo jẹ ki ọmọkunrin naa gba ominira ni Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹwaa, oṣu Kọkanla yii, wọn ni ko maa lọ lalaafia.
Ṣugbọn o jọ pe awọn ti wọn n tẹle ọmọkunrin yii ko pada lẹyin rẹ, tabi ko jẹ ojukokoro ati iwa ole to ti wọ ọ lẹwu ni. Bo ṣe tun di ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kejila, oṣu yii kan naa, ni ọmọkunrin yii tun gba ileeṣẹ awọn panapana to wa n’Ikẹja lọ, niṣe lo fo fẹnsi wọle, to si lọ sibi ọkan ninu awọn ọkọ ti wọn paaki sibẹ ti wọn n tunṣe lọwọ, lo ba yọ awọn ohun eelo ara ọkọ yii kan, n lawọn ọlọpaa ayaraṣaṣa (RRS) ba mu un.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin, ṣalaye pe wọn ti gbe ọmọkunrin naa lọ si ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ ni Panti, nibi ti iwadii yoo ti tẹsiwaju.