Lẹyin ọpọlọpọ ọdun to ṣegbeyawo, oṣere tiata yii bimọ obinrin

Jọkẹ Amọri

Titi di ba a ṣe n sọ yii ni awọn oṣere, awọn afẹnifẹre atawọn ololufẹ oṣere ilẹ wa to rẹwa daadaa nni, Tayọ Ṣobọla, ti gbogbo eeyan tun mọ si Ṣhogaga ṣi n ki i ku oriire fun ti ẹbun ọmọ tuntun ti Ọlọrun ṣẹṣẹ fi ta a lọrẹ.

Loootọ ni ọpọ eeyan ko fi bẹẹ gburoo oṣere yii nita bo ṣe maa n ṣe. Nitori ki i pẹ rara to fi maa n gbe aworan ara rẹ jade. Ṣugbọn ko ṣe gbogbo eleyii, nigba mi-in to ba si gbe aworan jade, ọpọ ni ki i mọ pe eyi to ti ya ko too loyun ni. Ko sẹni to gburoo rẹ tabi to ri i lasiko to loyun, afi bi aworan rẹ ṣe gba ori ayelujara kan lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹjọ, oṣu yii. Fidio asiko to wa ninu oyun lo kọkọ gbe sita, nibi to ti n jo. Bi awọn kan si ṣe ri i ni wọn ti n sọ pe pẹlu fidio ti Ṣotayọ gbe sita yii, o jọ pe o ti bimọ ni, nitori ki i ṣe ẹnikan to fẹran ariwo debi ti yoo gbe oyun to ni jade.

Bẹẹ gẹlẹ si lọrọ ri, nitori ko pẹ sasiko naa lo gbe aworan ibi to wa lọsibitu pẹlu ọmọ tuntun jojolo mọra.

Ọpọ awọn ololufẹ oṣere yii ni ko le pa ayọ naa mọra, gbogbo wọn ni wọn si n sọ pe aworan Ṣogaga tawọn ri yii jẹ eyi to dun mọ awọn ninu gidigidi.

Lara awọn oṣere ti wọn ti ii Tayọ ku oriire ni Fẹmi Adebayọ ti gbogbo eeyan tun mọ si Jẹili oniso. O ki i, o si kọ ọ sibẹ pe: ‘’Mo ki ẹ ku oriire o, Shotayọgaga, inu mi dun gidigidi si ọ, Ku oriire pe o sọ layọ. Mo gbadura pe ki Ọlọrun tubọ ro ọmọ rẹ lagbara, bo ṣe n dagba ninu ifẹ ati idẹra.

Bakan naa ni Bimbọ Ọṣin kọ ọ pe ‘’Jesu o ṣeun o. Ku oriire o, Ṣotayọgaga, fun ti ayọ abara tintin to wọle tọ wa. Mo ki ọ o, Ọmọọba-binrin mi, W a dẹni nla lorukọ Jesu. Bakan naa ni Muyiwa Ademọla ki i pe, ‘’Ku oriire o, Shottybaby. Inu wa dun gidigdi fun eleyii. O o ni i foju sunkun lori ayọ tuntun naa’’. Funkẹ Akindele ko gbẹyin ninu awọn to ki oṣere yii ku ayọ ọmọ tuntun naa. O kọ ọ pe ‘’Ku oriire o, arabinrin mi, Oluwa aa da ọmọ wa si’’.

Tẹ o ba gbagbe, ọkan ninu awọn ọba ilẹ Hausa ni Ṣotayọ fẹ ni nnkan bii ọdun diẹ sẹyin, ojuṣe Iya ọba yii ni ko jẹ ko fi bẹẹ maa kopa ninu ere. O ṣe diẹ ti oṣere yii ti n woju Oluwa fun ọmọ ki Ọlọrun too waa fi ọmọbinrin ta a lọrẹ bayii.

Leave a Reply