Lẹyin ọsẹ kan niluu oyinbo, Tinubu de lati gbọpa aṣẹ Naijiria

Faith Adebọla

 Aarẹ tuntun ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan nilẹ wa, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, ti ṣẹri pada de lati ilu oyinbo to rinrin-ajo lọ lọsẹ to kọja.

Irọlẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ogunjọ, oṣu Karun-un yii, ni baaluu to gbe ọkunrin ti wọn n pe ni Jagaban naa gunlẹ si papakọ ofurufu Nnamdi Azikiwe, niluu Abuja, lẹyin ọjọ mẹjọ to ti wa niluu London, lorileede United Kingdom.

Oun ati iyawo rẹ, Sẹnetọ Olurẹmi Tinubu, ni wọn jọ bọọlẹ ninu ọkọ ofurufu naa, nigba ti Igbakeji aarẹ aṣẹṣẹ dibo yan, Kashim Shettima, ti i ṣe gomina ipinlẹ Borno ana, lewaju awọn agbagba ẹgbẹ APC diẹ ti wọn lọọ ki wọn kaabọ ni papakọ ofurufu ọhun.

Ẹ oo ranti pe lọsẹ to lọ lọhun-un ni Agbẹnusọ fun Tinubu lori eto iroyin, Ọgbẹni Tunde Rahman, kede ninu atẹjade kan pe ọga oun n lọ silu oyinbo lati lọọ fara nisinmi diẹ ki iṣejọba rẹ too bẹrẹ ni pẹrẹ, ati pe Tinubu fẹẹ ṣe awọn ipade pataki kan lọhun-un, eyi to da lori bi ajọṣepọ olokoowo yoo ṣe sunwọn si i pẹlu awọn olokoowo ọhun.

Bo tilẹ jẹ pe awuyewuye ti n lọ lori ẹrọ ayelujara pe abẹwo Tinubu siluu oyinbo to di lemọ-lemọ lẹnu ọjọ mẹta yii ko ṣẹyin ailera baba naa, wọn ni ina aisan buruku kan n jo Tinubu labẹ aṣọ, ati pe iso inu ẹku ni wọn n fọrọ naa ṣe.

Ṣa, lasiko abẹwo rẹ to kẹyin yii, Tinubu gbalejo awọn eekan oloṣelu kan ti wọn lọọ ba a fikun lukun. Lara wọn ni oludije funpo aarẹ labẹ asia New Nigeria Peoples Party (NNPP), to tun ti figba kan jẹ gomina ipinlẹ Kano, Sẹneto Rabiu Musa Kwankwaso, ati Ọga agba ileefowopamọ agba nilẹ wa tẹlẹ, iyẹn Central Bank of Nigeria, Ọjọgbọn Muhammadu Sanusi. Wọn ko ti i sọ koko ohun ti ifikun lukun wọn da lori fawọn oniroyin.

Ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Karun-un ta a wa yii, ni ireti wa gẹgẹ bi ofin ṣe sọ, pe Tinubu yoo gbọpa aṣẹ iṣakoso orileede yii gẹgẹ bii aarẹ tuntun.
Ọjọ naa ni iṣakoso Aarẹ Muhammadu Buhari yoo tẹnu bọpo patapata, ti wọn yoo si bura fun aarẹ tuntun ati igbakeji rẹ, Kashim Shettima.

Irọkẹkẹ ati ipalẹmi gidigidi lo ti n waye nile ijọba apapọ l’Abuja, lori eto iburawọle naa.

Leave a Reply