Laaarọ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, lawọn aṣofin bii mẹtadinlogun, ninu awọn mẹẹẹdọgbọn ti wọn wa nile naa, yọ olori ileegbimọ ọhun ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan lọsẹ to kọja, Gboyega Aribiṣogun, ti wọn si yan Olubunmi Adeluga gẹgẹ bii olori wọn tuntun.
Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ to kọja ni wọn yan Abisogun to jẹ ọmọ bibi ilu Ijẹsa Iṣu Ekiti, nijọba ibilẹ Ikọle, to n ṣoju ẹkun kin-in-ni, ijọba ibilẹ Ikọle, lakooko ijokoo ile naa to waye ni gbọngan ile aṣofin wọn. Ọnarebu Tajudeen Akingbolu to wa lati ẹkun kin-in-ni ijọba ibilẹ Ariwa Ekiti, lo mu aba lati yan aṣofin naa wa, nigba ti Ọnarebu Adegoke Olajide to n ṣoju ẹkun ijọba ibilẹ Ẹfọn, kin in lẹyin. Bakan naa ni Ọnarebu Bọde Adeoye, to n ṣoju ẹkun keji ijọba ibilẹ Iwọ Oorun ipinlẹ Ekiti yan Arabinrin Olubunmi Adelugba, ti Ọnarebu Ojo Matins toun n ṣoju ijọba ibilẹ Ijero gbe e lẹyin.
Eyi lo fa a tawọn aṣofin naa fi dibo, Aribisọgan ni ibo mẹẹẹdogun, to fi fẹyin Adelugba balẹ.
Ṣugbọn l’Ọjọruu, Wẹside, iyẹn ọjọ keji ti iyansipo naa ṣẹlẹ ni wọn ni awọn kan ti wọn jẹ omọlẹyin gomina ipinlẹ naa tẹlẹ, Dokita Kayọde Fayẹmi, ti o si jẹ pe Adelugba ni wọn n ṣatilẹyin fun ya wọn ile-igbimọ naa, ni wọn ba bẹrẹ wahala, wọn ni awọn tọọgi oloṣelu kan fẹẹ dana sun apa kan ile naa nibi tọrọ ọhun le de.
Awọn agbofinro ni wọn tete lọ sibẹ ti wọn si gbakoso gbogbo agbegbe naa, ni wọn ba ti ile naa pa. Eyi ni ko fi ṣee ṣe fun awọn aṣofin naa lati jokoo, ti onikaluku awọn oṣiṣẹ si gba ile wọn lọ. Ṣugbọn ọrọ bẹyin yọ ni ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkanlelogun, oṣu yii, nigba ti awọn aṣofin naa tun pade, ti wọn si yọ Aribisọgan, ti wọn fi Adeugba rọpo rẹ.
Ṣugbọn aṣofin ti wọn yọ nipo naa naka abuku si Dokita Fayẹmi to ṣẹṣẹ kuro nipo gomina, o ni ọkunrin yii lo wa lẹyin bi wọn ṣe yọ oun nipo.
Ko ti i sẹni to mo boya yiyan ti wọn yan Adelugba yii yoo fopin si wahala ile naa.
Tẹ o ba gbagbe, iyansipo yii waye lẹyin iku olori wọn tẹlẹ, Họnọrebu Funminiyi Afuyẹ to ku lọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹwaa, ọdun yii.