Ọlawale Ajao, Ibadan
Awọn amòòkùṣìkà Fulani darandaran tun ti sọ̀kò ìbànújẹ sí agbagbe Ibarapa lẹẹkan sí i pẹlu bi wọn ṣe pa àgbẹ̀ oníkòkó kan, Ọgbẹni Bashiru Akinlọtan, sinu ọkọ ẹ niluu Igangan, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.
ALAROYE gbọ pe niṣe ni awọn Fulani ti ko sẹni to ti i ri wọn mu yii, dáná sun oko kòkó nla ti bàbá ẹni ọdun márùdínláàádọ́rin (65) naa n da lẹyin ti wọn gbẹmi ẹ sinu oko tan.
Wọn ní kò sí ojú ọgbẹ́ ibọn tabi ada lara baba naa. Eyi lo jẹ kí awọn eeyan fura pe o ṣee ṣe kó jẹ pé wọn fun un lọrun pa ni.
Nigba to n fìdí iṣẹlẹ yii múlẹ̀, Akọwe ẹgbẹ awọn agbẹ niluu Igangan, Ọgbẹni Taiwo Adeagbo, sọ pé Ọgbẹni Akinlọtan nikan lo da lọ sinu oko lọjọ naa, nitori naa, ko seni to le ṣalaye bi wọn ṣe pa a.
O ni ilẹ eékà mejila ni baba naa fi gbin kòkó ti awọn obayejẹ eeyan dana sun ọhun. Nitosi oko naa ni wọn sì ti ba oku rẹ̀.
Agbẹnusọ fún ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CSP Olugbenga Fadeyi, fidi ẹ mulẹ pé awọn ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ yii, ṣugbọn awọn ẹbi oloogbe ko fara mọ ki wọn gbe oku naa lọ sileewosan fún ayẹwo nitori ti wọn fẹẹ sin in kiakia.
Ni nnkan bíi aago mẹjọ alẹ ọjọ Wẹsidee to jade laye ọhún naa ni wọn sinkú ẹ nilana Musulumi.
Te o ba gbagbe, lọsẹ to kọja loludari ìkọ Amọtẹkun ni ipinlẹ Ọyọ, Ajagun-fẹyinti Ọlayinka Ọlayanju, sọ pé kò sí apaayan tabi ajinigbe kankan ni gbogbo agbegbe Ibarapa mọ bó tilẹ jẹ pé ojoojumọ lawọn ara agbegbe naa n sa, ti wọn ko le lọ sọko, bẹẹ ni wọn ko le lọ sodo, fún pipa ti awọn Fúlàní n pa wọn nipakupa.
O jọ pe nitori ariwo ti wọn n pa pe ko si Fulani apaayan mọ lo mu baba yii gbọna oko lọ to tun fi lọọ ko sọwọ wọn, ti wọn ṣeku pa a, ti wọn si tun dana sun eeka oko koko mejila.
Nitori wahala awọn Fulani darandaran yii naa nileegbimọ aṣòfin ipinlẹ Ọyọ ṣe fọwọ sí í pé kí ìjọba ipinlẹ naa ṣàgbékalẹ̀ igbimo ti yóò máa mú àwọn tó bá tàpá si ofin ti ìjọba ṣe lọdun to koja, eyi to ṣe é leewọ fún ẹnikẹni lati maa da maaluu tabi ohun ọsin kankan kiri lati le dekun wahala to máa n waye laarin awon Flulani darandaran.