Olu-Theo Omolohun, Oke-Ogun.
Aṣeyọri nla ni fawọn ẹṣọ fijilante ilu Isẹyin, lagbegbe Oke-Ogun, nipinlẹ Ọyọ, latari bọwọ wọn ṣe tẹ awọn afurasi Bororo ti wọn ni wọn sa kuro lọgba ẹwọn Abolongo, niluu Ọyọ ti wọn si tun lọọ jale lẹyin ti wọn kuro nibẹ.
Gẹgẹ bi Jowuro awọn Fulani agbegbe Oke Ogun, Abubakar Baani, ṣe fiṣẹlẹ naa to ALAROYE leti niluu Isẹyin, o ni deede aago marun-un irọlẹ ọjọ Ẹti, Furaide, to kọja ni olobo ta awọn pe awọn ọmọ Fulani keekeekee kan wa nile itura Class, to wa lọna Peller, niluu naa, nibi ti wọn ti n jaye bii ẹni jẹ’ṣu.
O ni kia loun ti pe awọn ẹṣọ alaabo fijilante, VGN, ti wọn si ka wọn mọ’bẹ, mẹrin ni wọn, ṣugbọn awọn obinrin meji aarin wọn raaye sa lọ, ti ọwọ si tẹ ọkunrin meji, Mohammed Shagari, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn (33) ati Mohammed Usman, ẹni ọgbọn ọdun (30), ti wọn jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Kogi.
Nigba ti wọn ko wọn de teṣan ọlọpaa to wa lọna Okeho, ti wọn si fọrọ wa wọn lẹnu wo, lawọn afurasi ọdaran naa jẹwọ pe awọn wa lara awọn ẹlẹwọn to sa kuro lọgba ẹwọn Abolongo, niluu Ọyọ, ati pe fọto awọn wa lara awọn ẹlẹwọn tawọn agbofinro n wa latigba naa.
Wọn lọkunrin naa tun jẹwọ pe iṣẹ adigunjale lawọn n ṣe, iṣẹ naa lo si sọ awọn dero ẹwọn, ṣugbọn lẹyin ti wọn sa jade ọhun, niṣe ni wọn tun pada sidii iṣẹẹbi wọn.
Wọn lawọn afurasi ọdaran naa jẹwọ pe laipẹ yii lawọn gba miliọnu mẹjọ o le diẹ lọwọ oniṣowo ilu Idah, nipinlẹ Kogi, awọn si tun jale miliọnu meji aabọ naira lọwọ ẹlomi-in, lara owo ọhun lawọn ti lọọ ra alupupu Honda TVS tuntun meji tawọn n gun kiri lẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹrin Naira (#700,000).
Abubakar ni gbara ti wọn ti fọrọ ọhun to oun leti loun ti pe ọga ọlọpaa teṣan Isẹyin lati le fọwọ sowọ pọ pẹlu awọn, ṣugbọn nigba ti wọn ko tete dahun lo mu ki awọn ke si ikọ ọlọpaa to n gbogun ti iwa ijinigbe nipinlẹ Ọyọ (Anti Kidnapping Squad) AKS, to wa lagbegbe Dugbẹ, niluu Ibadan, ti wọn si waa ko gbogbo awọn tọwọ tẹ naa lọ fun iwadii.