Faith Adebọla
Kayeefi ni ọrọ ọkunrin kan ti wọn pe ni babalawo, Jimoh Jogbo, ẹni ọdun mejidinlogoji, to pa iya iyawo rẹ, Fatimọ Muskilu, ẹni ọdun mẹrindinlaaadọta ati ọrẹ rẹ, Shakiru Jamiu, ẹni ogoji ọdun, lẹyin to fipa ba aburo iyawo rẹ ti ko ju ọmọ ọdun mẹrinla lọ lo pọ tan nile wọn to wa ni Opopona Orodana, niluu Olofun, n’Ibẹju Lẹkki.
ALAROYE gbọ pe ilu Agọ-Iwoye, nipinlẹ Ogun, ni ọkunrin babalawọ yii ati iyawo rẹ n gbe ki wọn too pinnu lati wa si ilu Eko. Ṣugbọn nitori ko si owo ti wọn le fi gbale lọwọ wọn ni tọkọ-tiyawo yii fi n gbe nile iya iyawo wọn to wa ni Ibẹju Lẹkki yii, lati inu oṣu Kẹta, ọdun yii.
Ki i ṣe Jogbo ati iyawo rẹ nikan ni wọn jọ n gbele ana rẹ yii. A gbọ pe awọn aburo iyawo meji mi-in naa n ba wọn gbe ninu ile ọhun pẹlu mama wọn. Ṣugbọn ninu ile ana ni Jogbo ti jẹ nnkan eewọ, to fipa ba aburo iyawo rẹ ti ko ju ọdun mẹrinla lọ lo pọ.
ALAROYE gbọ pe ninu oṣu Kẹwaa, ọdun yii, ni ọkan ninu awọn ọmọ mama yii bimọ, lo ba lọọ ba a ṣe ọlọjọjọ ọmọ, eyi lo fi fi awọn ọmọ rẹ obinrin meji sile pẹlu tọkọ-taya naa.
Obinrin yii ṣalaye pe ni ọjọ kẹfa, oṣu Kọkanla, ọdun yii, ọkan ninu awọn aburo oun meji tawọn jọ wa ninu ile lọ si iṣọ oru, ṣugbọn ekeji wa nile, oun ko lọ ni tiẹ. O ni nigba to to nnkan bii aago mọkanla, oun ati ọkọ oun jọ wa nita, ṣugbọn nitori pe o n ba ẹnikan sọrọ lori foonu loun ṣe fi i silẹ ti oun wọle lọ ni toun.
Nigba to si pẹ diẹ ni ọkọ oun waa ba oun ninu ile, to si sun si ẹgbẹ oun. Ṣugbọn si iyalẹnu oun, nigba to di aarọ ọjọ keji ni aburo oun waa sọ fun oun pe ọkọ oun fipa ba oun lajọṣepọ loru ọjọ naa. Bo ṣe sọ fun aunti rẹ naa lo sọrọ yii fun mama wọn. O jọ pe ko too wọle lọọ ba iyawo rẹ pada lo ti ki aburo iyawo rẹ yii mọlẹ, to si fipa ba a lo.
Ọrọ yii bi obinrin naa ninu, lo ba lọọ gbe ọrọ naa ko ọkọ re loju, ṣugbọn o ṣẹ kanlẹ pe oun ko ṣe ohun to jọ bẹẹ.
Iyawo Jimoh ni, ‘‘Loju-ẹsẹ ni mo pe mama mi ti mo si ṣalaye fun wọn, inu bi awọn naa fun iwa buruku to hu ọhun, la ba ni ko ko ẹru rẹ ko kuro nile wa. Aarọ ọjọ keji lo ko ẹru rẹ, to si lọ, o ni oun n pada si Agọ-Iwoye. Afi bo ṣe tun pada wa laarin ọsẹ yẹn to bẹrẹ si i bẹ mi pe ki n dariji oun. Ṣugbọn gbogbo ẹbẹ to n bẹ pe ka ma jẹ ki ọrọ naa de agọ ọlọpaa ko ba mama mi nile, gbogbo wa ko tiẹ fara mọ ọn paapaa. Eyi lo mu ki n gba agọ ọlọpaa, ẹka ti Akọdo lọ, ti mo si fi iroyin naa to wọn leti.
‘‘Ṣọọṣi Sẹlẹ to wa ni White House, Orofun, ni Ibeji Lẹkki, ti wọn ti maa n jọsin ni mama mi pada si nigba ti wọn de lati ibi ti wọn ti lọọ ba wọn ṣẹ ọlọjọjọ ọmọ.
‘‘Ni nnkan bii aago mẹta oru ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹrinla, oṣu Kọkanla yii, ni ẹnikan pe mi lati ṣọọṣi mama mi pe ki n maa bọ, o ni ara wọn ko ya. Bi mo ṣe fẹẹ maa sare lọ sibẹ ni mo n gbọ iro ẹsẹ lẹnu ọna, nigba ti mo si jade, irin nla kan ni mo ba nilẹẹlẹ lẹnu ọna.
‘‘Bi mo ṣe n lọ si ṣọọṣi naa ni wọn tun pe mi pe Ọsibitu Jẹnẹra Akodu ni ki n maa lọ. Ibẹ ni mo ti pada mọ pe Jogbo ti pa mama mi, o si tun fẹẹ waa pa emi naa’’.
A gbọ pe nigba ti Jogbo lọ sinu ṣọọṣi lati pa iya iyawo rẹ yii ni ọkan ninu awọn olujọsin, to tun jẹ ọrẹ rẹ, Shakiru Jamiu, ri i. Nitori pe o da a mọ, ati pe o ṣee ṣe ko ṣofofo ọrọ yii lo fi pa ọrẹ rẹ yii naa. Igi nla to la mọ iya iyawo rẹ lori to fi ku naa lo la mọ oun paapaa lori. Ko si ju bii ibusọ mẹfa si ṣọọṣi naa to pa ọkunrin yii si nibi ti wọn ni iyẹn ti n sa lọ.
Ọpẹlọpẹ awọn ọdẹ adugbo ti wọn tete ke si pe ki wọn maa foju lede lati ri i pe wọn ri babalawo naa mu. Lẹyin-o-rẹyin ni wọn mu un, ti wọn si fa a le ọlọpaa lọwọ.