Jamiu Abayọmi
Gomina ipinlẹ ipinlẹ Eko, Babajide Oluṣọla Sanwo-Olu, ti buwọ lu iyansipo Shuaheeb Ọlabọde Agoro, gẹgẹ bii olori awọn oṣiṣẹ nipinlẹ Eko, ẹlẹẹkejilelogun, ti iṣẹ rẹ yoo si bẹrẹ l’ọgbọnjọ, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2023 yii.
Ninu atẹjade kan ti Akọwe gomina lori eto iroyin, Gboyega Akọsilẹ, fi lede lorukọ olori awọn oṣiṣẹ to n kogba wọle, Ọgbẹni Hakeem Muri-Okunọla, lo ti fidii ẹ mulẹ pe Ọgbẹni Agoro ti wa lẹnu iṣẹ ọba lati ọjọ kin-ni, oṣu Keje, ọdun 2003, to si n ni agbega lẹnu iṣẹ naa titi to fi ga depo akọwe agba lọjọ kẹta, oṣu Kẹjọ, ọdun 2015, ipo to wa titi di asiko iyansipo rẹ yii.
Ọga agba yii waa ke si gbogbo awọn ẹka nileeṣẹ ijọba ipinlẹ naa lati fọwọsowọpọ pẹlu olori awọn oṣiṣẹ tuntun yii, ko le gbe wọn de ebute ogo. O tun waa gbadura fun Agoro pe ki Ọlọrun pẹlu rẹ, ko si ṣe aṣeyọri lọfiisi rẹ tuntun yii.
“Lai ni i fakoko kankan ṣofo mọ, gbogbo ileeṣẹ ijọba gbọdọ maa ṣe deedee pelu ọga wọn yii, ki wọn ṣe akoyawọ pẹlu rẹ, ki wọn na tan, lai fi ohunkohun pamọ fun un, ki wọn si tun maa fi tọkan tara ṣiṣẹ to ba yan fun wọn lati ṣe’’.
Tẹ o ba gbagbe, aipẹ yii ni Aarẹ orileede yii, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, yan Ọgbẹni Muri-Okunọla, ti i ṣe olori awọn oṣiṣẹ ipinlẹ naa gẹgẹ bii akọwe rẹ ti wọn yoo jọ ṣiṣẹ pọ. Fun idi eyi lo ṣe kọwe fipo silẹ nileeṣẹ ijọba ipinlẹ Eko, ti yoo si darapọ mọ ijọba Tinubu lọjọ kọkandilọgbọn, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii.