Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Awọn oṣiṣẹ kaakiri ipinlẹ Ogun ti fagi le iyanṣelodi ti wọn bẹrẹ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.
Igbesẹ yii waye lẹyin tawọn aṣoju ajọ oṣiṣẹ tọwọ bọwe adehun igbọra-ẹni-ye pẹlu ijọba lẹyin ipade mi-in ti wọn tun ṣe lọfiisi gomina l’Oke-Mosan lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kejidinlogun, oṣu kẹsan-an, ọdun yii.
Koda, ẹkunwo ti wọn ti ni inu oṣu kọkanla nijọba yoo bẹrẹ ẹ paapaa, oṣu kẹwaa to n bọ yii ni wọn yoo bẹrẹ si i san an bayii.
Lara awọn nnkan ti wọn fẹnu ko si ninu ipade naa ni :
Sisanwo oṣu ẹlẹgbẹrun lọna ọgbọn fun oṣiṣẹ to kere ju ti yoo bẹrẹ lati oṣu kẹwaa, ọdun 2020. Igbega fawọn to yẹ fun lati ọdun 2018 yoo bẹrẹ lẹsẹkẹsẹ, owo ajẹmọnu ati wiwọ ọkọ BRT yoo bẹrẹ loṣu kin-in-ni, ọdun 2021.
Awọn to ṣoju ijọba nibi ipade yii ni: Olori awọn oṣiṣẹ nipinlẹ Ogun; Alaaji Salisu Shuaibu, Tokunbọ Talabi; Akọwe ijọba fun Gomina Dapọ Abiọdun ati Pasitọ Rẹmi Hazzan ti i ṣe oludamọran pataki fun gomina lori eto iroyin, nigba ti awọn olori awọn oṣiṣẹ naa ko gbẹyin pẹlu.