Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ọwọ ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti tẹ ọmọkunrin ẹni ogun ọdun kan, Josiah Godwin, lori ẹsun pe o ṣeku pa ọga rẹ, Ọgbẹni Savior Joseph, to si tun ju oku rẹ sinu kanga lẹyin to pa a tan.
ALAROYE gbọ pe iṣẹlẹ naa waye nibi tawọn mejeeji ti n ṣiṣẹ lagbegbe Ìmàfọ̀n, Akurẹ, nijọba ibilẹ Guusu Akurẹ, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ to kọja.
Ẹgbọn oloogbe, Ọgbẹni Odey Julius Ọgbaji, ṣalaye fawọn oniroyin pe iṣẹ POP, iyẹn awọn to n fi simẹnti da ọkan-o-jọkan ara sara soke aja ile ni aburo oun n ṣe, ti awọn si mọ afurasi ọdaran naa mọ oloogbe yii gẹgẹ bii ọmọ ẹkọṣẹ to n kọṣẹ lọdọ rẹ.
O ni oun ati aburo oun ṣi jọ sọrọ nigba to pe oun sori aago laaarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ṣugbọn ti nọmba rẹ ko wọle mọ lati aarọ Ọjọruu, Wẹsidee, ti oun ti n pe e pada.
Ọgbaji ni oun ko kọkọ fi bẹẹ ja kinni ọhun kunra nitori ṣe loun ro pe boya ina lo ku patapata lori foonu rẹ.
Ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ ọhun kan naa lo ni aburo awọn kan, iyẹn ẹni ti wọn bi tẹle oloogbe tun pe oun, to si n beere boya oun gburoo Joseph, nitori gbogbo akitiyan oun lati ri i ba sọrọ lo ja si pabo.
O ni lẹyin-o-rẹyin lawọn gbiyanju lati ṣawari Josiah, iyẹn ọmọọṣẹ rẹ lọnakọna, ti awọn si beere bi ọga rẹ ṣe rin lọwọ rẹ.
Alaye ti ọmọkunrin naa ṣe fun awọn ni pe ṣe lọga oun deedee ji oun dide lati oju oorun loru ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, to si fọ foonu oun mọlẹ, lẹyin eyi lo ni o ki oun mọlẹ, to si bẹrẹ si i lu oun bii kiku, bii yiye, ko too paṣẹ foun lati lọọ sun pada loru ọjọ yii.
Josiah ni bi ilẹ ṣe mọ loun ti kẹru oun, ti oun si sa kuro nibi tawọn ti n ṣiṣẹ nigba ti oun ṣakiyesi pe ọga oun ti wa ninu ile igbọnsẹ.
Ẹgbọn oloogbe ni afurasi ọdaran naa ko ri esi gidi kan fun awọn nigba tawọn beere idi to fi sa kuro ni saiti ti wọn ti n ṣiṣẹ lai ri ọga rẹ ṣoju. Ati ibeere tawọn tun bi i pe ki lo de to pa foonu rẹ ti awọn eeyan ko fi ri i pe, ati idi to fi dakẹ jẹẹ lai sọ fun ẹnikẹni nigba ti ko ri ọga rẹ ti wọn jọ lọ sibi iṣẹ?
O ni nibi tọrọ ọhun ya awọn lẹnu de, ko si oju fifọ kankan lara gilaasi foonu to ni oloogbe fọ mọlẹ to fi ni o mu ki oun binu sa kuro ni saiti.
O ni lẹyin ọjọ kẹrin lawọn ṣẹṣẹ ṣawari ọkunrin ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn ọhun ninu kanga ti ọmọ iṣẹ rẹ ju u si lẹyin to pa a tan, n lawọn ba lọọ fi iṣẹlẹ naa to awọn ọlọpaa leti.
Nigba to n fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ, Alukoro ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Abilekọ Funmilayọ Ọdunlami, ni afurasi naa ṣi wa lọdọ awọn ti awọn n fọrọ wa a lẹnu wo lọwọ.
O fi kun un pe ni kete ti iwadii ba ti pari lori ọrọ rẹ lawọn yoo foju rẹ bale-ẹjọ.