Lẹyin ti Oyetọla ko wọle l’Ọṣun lo ya biliọnu mejidinlogun Naira ni banki- Adeleke

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Gomina ipinlẹ Ọṣun, Sẹnetọ Ademọla Adeleke, ti sọ pe inu agbami gbese nijọba ana tipinlẹ Ọṣun si lẹyin ti wọn ko wọle lasiko idibo to waye ninu oṣu Keje ọdun yii.lulẹ loṣu keje ọdun yii.

Lasiko ti Adeleke n ṣalaye gbese to ba lọfiisi fun awọn lọbalọba nipinlẹ Ọṣun lọsan-an Ọjọbọ, Tọsidee, lo sọ pe ni kete ti Alaaji Gboyega Oyetọla fidi-rẹmi ninu idibo gomina lo lọọ ya biliọnu lọna mejidinlogun Naira.

O ni akọwe-owo funpinlẹ Ọṣun lo fun oun ni atupalẹ awọn gbese naa lọgbọn oṣu Kọkanla, ọdun yii, nibẹ laṣiiri ti tu pe biliọnu lọna irinwo o le meje Naira lapapọ gbese tipinlẹ Ọṣun jẹ.

Yatọ si gbese owo-osu awọn oṣiṣẹ ijọba ati ajẹmọnu awọn oṣiṣẹ-fẹyinti, oriṣiiriṣii gbese nijọba ana tun jẹ, to si jẹ pe odidi ọdun mejidinlọgbọn ni wọn yoo fi san an pada.

O ni ijọba ana ko ṣeto kankan silẹ lori bi wọn ṣe fẹẹ maa san owo naa pada. O ni nigba ti oun ati igbakeji oun de ọfiisi lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun yii, awọn ko ba eepinni ninu akanti ijọba.

Adeleke ni, ‘Gẹgẹ bii gomina yin, mo nilo lati beere ibeere, mo si nilo idahun. Gomina Oyetọla gbọdọ ṣalaye fun wa, ibi tijọba rẹ na biliọnu lọna ojilelọọọdunrun-un o din mẹsan-an Naira si.

‘Bakan naa ni awọn ti wọn ya wọn lowo, paapaa, awọn banki gbọdọ ṣalaye fun wa, idi ti wọn fi ya ijọba kan lowo ti yoo fi odidi ọdun mejidinlọgbọn san.’

Leave a Reply