Gbenga Amos, Abẹokuta
Wasiu Ọpẹyẹmi lorukọ ọkunrin ẹni ọdun mẹtadinlogoji yii, ẹni keji ẹ ni Noah Isreal, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn. Tẹwọn de lawọn mejeeji, iṣẹ adigunjale ti wọn tori ẹ ran wọn lẹwọn lọjọsi naa ni wọn tun pada si, ṣugbọn ọwọ palaba wọn ti segi, wọn si ti wa kololo ọlọpaa bayii.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, to fi ọrọ yii ṣọwọ s’ALAROYE ninu atẹjade kan sọ pe Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹfa yii, lọwọ ba awọn afurasi ọhun lọna marosẹ Eko si Ibadan, nigba ti wọn n bọ lati oko ole ti wọn lọọ ja l’Ọyọọ.
Ọkada lawọn mejeeji gun lọjọ naa, bi wọn ṣe mura, ati bi wọn ṣe n gun ọkada, lo fu awọn ikọ ọlọpaa to n gbogun ti iwa ijinigbe lọna marosẹ ọhun lara, ni wọn ba le wọn mu.
Wasiu jẹwọ pe ọmọ bibi ilu Ijẹbu-Ode loun, ṣugbọn ọmọ ipinlẹ Benue ni Noah, wọn ni ilu Ogbomọṣọ lawọn ti n bọ, awọn o si ba iṣẹ meji lọ sibẹ ju idigunjale lọ.
Wọn ni gbogbo nnkan to wa lọwọ awọn yii, oko ole naa lawọn ti ri i, wọn tun jẹwọ pe awọn fi tipatipa mu ọkan ninu awọn ti wọn ja lole lati fi ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un Naira ṣọwọ si akaunti awọn, tori onitọhun ko ni dukia tawọn le ji, lawọn ṣe ni ko fowo naa ranṣẹ.
Wọn tun jẹwọ pe ọgba ẹwọn Ọba, nipinlẹ Ogun, lawọn mejeeji ti pade, ọrẹ ki i si ya ọrẹ, nigba tawọn pari saa ẹwọn awọn tan lawọn tun gbegba idigunjale pada.
Ṣa, awọn mejeeji ti wa lakata awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ bayii, wọn si ti n ba iwadii lọ lori ọrọ wọn.