Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ni ile-ẹjọ Majistreeti kan to fi ilu Ilọrin, ṣe ibujokoo paṣẹ pe ki wọn sọ Fulani darandaran meji, Ali Mohammadu, ẹni ọdun mẹrinlelogun, ati Sidi Abubakar, ẹni ọdun mejila, sẹwọn Oke-Kura, fẹsun pe wọn seku pa agbẹ kan Danjuma Maidanji, ti wọn si ṣe ọmọ rẹ obinrin Mariam, leṣe lẹyin ti wọn fi ẹran jẹko wọn tan.
Awọn afurasi darandaran naa ni wọn ṣeku pa agbẹ naa, ti wọn si ṣe ọmọ rẹ obinrin leṣe nitori pe wọn fẹsun kan awọn Fulani darandaran yii pe wọn n fi ẹran jẹ oko awọn. Ẹsun meji ni wọn ka si awọn afurasi naa lọrun. Akọkọ ni pe wọn pawọ-pọ huwa ọdaran, ekeji ni ẹsun ipaniyan, eyi to ta ko iwe ofin ilẹ wa, ori kẹtadinlọgọrun-un ati igba-le-mọkanlelogun (97and 221). Inu
Oko ni agbẹ atọmọ rẹ yii wa tawọn Fulani fi lọọ kọ lu wọn.
Agbefọba, Ayeni Gbenga, rọ ile-ẹjọ ko fi awọn afurasi mejeeji sahaamọ, nitori iwa ọdaran paraku ni wọn hu. Adajọ Dasuki gba ẹbẹ agbefọba yii wọle, lẹsẹkẹsẹ lo paṣẹ pe ki wọn lọọ ju awọn afurasi naa si ọgba ẹwọn Oke-Kura, o waa sun igbẹjọ si ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2023.