Lẹyin ti wọn gbowo, ajinigbe tu awọn ọmọ iya mẹta ti wọn gbe silẹ

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Awọn agbebọn to ji ọmọ mẹta kan gbe lagbegbe Aboto si Ajelanwa, nijọba ibilẹ Asa, nipinlẹ Kwara, ti tu wọn silẹ lẹyin ti wọn gba miliọnu kan ati igba Naira (1.2 million), owo itusilẹ lọwọ mọlẹbi.

Tẹ o ba gbagbe lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ to kọja, lawọn afurasi ajinigbe kan kọ lu arakunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Fatai atawọn ọmọ rẹ keekeeke meji, AbdulBasit ati Ramọta, loko kasu, lopopona to lọ lati Aboto-Ọja si Ajelanwa, nijọba ibilẹ Asa, nipinlẹ Kwara, ti wọn si ji awọn ọmọ mẹta naa gbe lọ.

Arakunrin Fatai, to ba oniroyin sọrọ sọ pe ni nnkan bii aago mẹji ọsan ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ to kọja, ni awọn ajinigbe naa waa ba oun ninu oko toun ti n ṣa kaju, iro ẹsẹ lo ni oun n gbọ, ṣugbọn nigba ti oun gbe oju soke loun ri awọn ajinigbe mẹfa kan pẹlu ibọn Ak-47, ti oun si bẹrẹ si i sa lọ sọna Aboto-Ọja, toun si fi awọn ọmọ oun keekeeke mẹta silẹ sinu ọkọ ayọkọlẹ oun.

O tẹsiwaju pe oun pada mori bọ, ṣugbọn wọn ji awọn ọmọ oun mẹtẹẹta ko lọ. Fatai ni nigba ti oun sa lọ loun pade baba kan to n ta ẹyin, ọkọ baba ẹlẹyin yii loun wọ, to si gbe oun lọ si Aboto-Ọja.

Awọn ajinigbe naa pada pe awọn mọlẹbi, ti wọn si beere miliọnu mẹwaa Naira lori ọmọ kọọkan gẹgẹ bii owo itusilẹ. Awọn mọlẹbi ko ri owo naa san lati ọsẹ to kọja, ni wọn ba ni ki wọn ko iye ti wọn ba ni lọwọ wa, tori pe awọn fẹẹ lọọ gba awẹ Ramadana niluu awọn. Bayii ni awọn mọlẹbi ṣa miliọnu kan ati ẹgbẹrun lọna igba Naira (1.2 m), jọ ti wọn si lọọ ko fun awọn ajinigbe naa, ni wọn ba yọnda awọn ọmọ mẹtẹẹta yii.

 

Leave a Reply