Lẹyin ti wọn yọ alaga PDP nipo, wọn ti pe Fayọṣe atawọn yooku ẹ pada sinu ẹgbẹ 

Adewale Adeoye

Ki ẹgbẹ le wa ni iṣọkan lati le ni ilọsiwaju daadaa, awọn agba ẹgbẹ oṣelu PDP ti kede pe gbogbo awọn aṣaaju ẹgbẹ naa bii, gomina ipinle Ekiti tẹlẹ, Ọgbẹni Ayọdele Fayọṣe, gomina ipinlẹ Katsina tẹlẹ, Ibrahim Shema, Sẹnetọ Pius Anyim Pius, Ọjọgbọn Dennis Ityavya pẹlu Dokita Aslam Aliyu, ti wọn fofin de pe wọn n ṣoju meji pẹlu ẹgbẹ nigba iṣakoso alaga wọn tẹlẹ, Iyorchia Ayu, ni alaga tuntun ti sọ pe ki gbogbo wọn patapata pada sinu ẹgbẹ naa loju-ẹsẹ.

Tẹ o ba gbagbe, laipẹ yii ni wọn fofin de gbogbo awọn agba oloṣelu naa, lẹyin ti wọn fẹsun ṣeyi-ṣọhun kan wọn.

Yatọ si awọn agba ẹgbẹ ọhun ti wọn roju rere ẹgbẹ naa bayii, wọn tun ti sọ pe wọn yoo gbe ẹsun ti wọn fi kan gomina ipinlẹ Benue, Samuel Ortom, yẹwo daadaa, ko too di pe o waa jẹjọ niwaju igbimọ amuṣẹṣe ẹgbẹ naa ti wọn fiwe pe e tẹlẹ.

Alukoro ẹgbẹ oṣelu PDP, Ọnarebu Debọ Ologunagba, to sọrọ naa di mimọ lakioko to n ba awọn oniroyin sọrọ niluu Abuja, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yiisọ pe ẹgbẹ PDP ti ṣetan bayii lati sa gbogbo agbara wọn pata lati ri i pe wọn gba gbogbo ẹtọ awọn ọmọ ẹgbẹ naa pada fun wọn, paapaa ju lọ, ẹtọ gbogbo awọn oloṣelu ti wọn dije dupo pataki ninu awọn eto idibo to waye gbẹyin nilẹ yii.

O tẹsiwaju pe oniruuru awọn nnkan ti yoo mu ilọsiwaju daadaa ba ẹgbẹ naa lawọn igbimọ agba ẹgbẹ naa sọrọ le lori ninu ipade pataki wọn kan to waye l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọgbọnjọ, oṣu Kẹta, ọdun yii, ti wọn si ti fẹnu ko pe afi ki wọn yaa tete bẹrẹ iṣẹ lori awọn nnkan naa ni kiakia.

Ologunagba ni ki ilọsiwaju to ye kooro le wa ninu ẹgbẹ naa lawọn ṣe tete pe gbogbo awọn agba ẹgbẹ ọhun pada, ati pe igbesẹ tawọn agba ẹgbẹ ọhun gbe lori bi wọn ti ṣe pe awọn aṣaaju ẹgbẹ yii pada ki i ṣe lati fi tabuku awọn igbimọ amuṣẹṣe rara, nitori pe ofin ko faaye gba a rara pe ki ẹnikẹni tapa sofin ẹgbẹ, paapaa ju lọ fawọn to ba n ṣoju meji pelu ẹgbẹ, gege bo ti ṣe wa ninu iwe ofin ẹgbẹ naa.

Lorukọ igbimọ amuṣẹṣe ẹgbẹ PDP, Ologunagba rọ gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ pe ki wọn ma ṣe tapa sofin ẹgbẹ nigba kankan, ati pe ẹgbẹ paapaa ti ṣetan lati pari gbogbo ija yoowu to ba wa laarin awọn ọmọ ẹgbẹ gbogbo.

Ologunagba ni, “Ẹgbẹ PDP gbọdọ wa ni iṣọkan nigba gbogbo, ki wọn baa le gba ẹtọ wọn pada lọwọ awọn ẹni ti wọn fi ọna eru gba a lọwọ wọn”.

Lara awọn ẹtọ ti agbẹnusọ ẹgbẹ yii sọ pe wọn yoo gba pada ni bi wọn ti ṣe ṣeru fun Alaaji Atiku Abubakar ninu ibo aarẹ to waye lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keji, ọdun yii.

Ka ranti pe laipẹ yii ni wọn fofin de awọn marun-un kan ninu ẹgbẹ PDP, ẹsun ti wọn fi kan wọn ni pe wọn tapa sofin ẹgbẹ.

Lọsẹ to kọja lọhun-un lawọn ọmọ ẹgbẹ PDP wọọdu ti alaga ẹgbẹ naa tẹlẹ, Sẹnetọ Iyorchia Ayu, ti wa yọ ọ danu pe ko tọ lẹni to le wa nipo alaga ẹgbẹ naa. Igbesẹ yii ni Ayu ni ko yẹ ki wọn gbe, eyi lo jẹ ko gba ile-ẹjọ lọ pe ki kootu le da a pada sipo rẹ.

Loju-ẹsẹ ni wọn ti yan Alaaji Umar Damagum, rọpo rẹ, to si ti n paṣẹ gẹgẹ bii alaga tuntun. Lara igbesẹ to gbe bayii ni bo ti ṣe da gbogbo awọn agba ẹgbẹ maraarun tijọba Ayu le danu kuro lẹgbẹ pada sinu ẹgbẹ naa.

Leave a Reply