Gbenga Amos, Ogun
Baba ẹni ọdun mọkandinlogoji kan, Jeremiah Mfon, ti n wolẹ ṣun un lakolo awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ lolu ileeṣẹ wọn latari bo ṣe ki ọmọ bibi inu rẹ ti ko ju ọdun mẹtala lọ mọlẹ, to si fun un loyun, o lepe lo n ja oun.
Iya ọmọbinrin ti wọn forukọ bo laṣiiri ọhun lo lọọ fẹjọ sun lẹka ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Mowe, o loun fura si iṣesi ọmọ oun lẹnu ọjọ mẹta yii pe ara ọmọ naa ko ya gaga, ẹẹmẹwaa lo n tutọ, loun ba pe e, oun tẹ ẹ ninu, ibẹ loun ti mọ pe o ti fẹra ku.
O lọmọ naa jẹwọ foun pe baba oun lo ba oun laṣepọ, oun lo si foun loyun. Wọn mu ọmọ yii lọ sọsibitu, ayẹwo si fidi ẹ mulẹ pe loootọ loyun oṣu mẹrin ti duro si i lara.
Loju-ẹsẹ ti DPO teṣan Mowe, SP Fọlakẹ Afẹnifọrọ, gbọrọ yii lo ti ran awọn ọmọọṣẹ rẹ lati lọọ mu afurasi ọdaran ọhun wa, wọn si ri i mu.
Nigba ti wọn n bi i leere ohun to jẹ yo to jẹ ọmọ bibi inu ẹ ni ibasun kan, o ni ki wọn ṣe oun jẹẹjẹ, o ni ki i ṣe oju lasan lọrọ yii, epe lo n ja oun. O loju ala loun wa lọjọ tiṣẹlẹ ọhun waye, oun lalaa pe oun n ṣe kerewa fun iya ọmọ yii to ti kọ oun silẹ tipẹ ni, afi boun ṣe ji saye to jẹ ori ọmọ oun loun ba ara oun, ọmọbinrin naa loun n ṣe ‘kinni’ fun.
Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, CP Lanre Bankọle, ti ni ki awọn ọtẹlẹlẹmuyẹ lẹka ti wọn ti n gbogun ti fifọmọde ṣowo ẹru tubọ ṣewadii ijinlẹ lori iṣẹlẹ yii. O nile-ẹjọ lo ṣi maa pinnu boya alaye afurasi ta leti abi ko ta, ti wọn yoo si ṣedajọ to yẹ fun un.