Adewale Adeoye
Beeyan ba loun ko ni i rẹrin-in, ita gbangba lo maa ba ẹyin rẹ, pẹlu ọrọ tiyawo ile kan, Abilekọ Rahinat Ahmed n sọ ni kootu kọkọ-kọkọ ‘Grade 1’, to wa lagbegbe Kubuwa, niluu Abuja nigba to loun fẹẹ kọ ọkọ oun.
Niṣe ni Rahinat n bẹ adajọ ileẹjọ naa, Onidaajọ Malam Ibrahim Rufai, pe ko tu igbeyawo ọdun mẹrinla to wa laarin oun ati ọkọ oun ka ni kiakia. Iyaale ile yii loun ko nifẹẹ ọkọ oun mọ rara, bo tilẹ jẹ pe ọmọ mẹjọ lo ti bi fun un.
Ninu ọrọ rẹ nileẹjọ naa, Rahinat ni oun ko fẹẹ gbe papọ pẹlu ọkọ oun yii mọ rara, nitori ko si ifẹ kankan mọ laarin awọn mejeeji, ati pe oun ti ṣetan lati sanwo ori tọkọ oun san fawọn ẹbi oun lakooko to fẹẹ fẹ oun sile gẹgẹ bii aya.
Rahinat ni, ‘‘Bii ẹni pe mo n fiya nla jẹ ara mi ni bi mo ba tun ṣi n gbẹ lọdọ ọkọ mi yii.Mo ti ṣetan lati san ẹgbẹrun marun-un Naira fun un pada, iyẹn owo-ori to san fawọn ẹbi mi lakooko to fẹẹ fi mi ṣaya.
‘‘Ọmọ mẹjọ ni mo ti bi fun un, ṣugbọn mi o nifẹẹ rẹ mọ bii igba ta a kọkọ fẹra wa sile’’.
Adajọ ileẹjọ naa, Onidaajọ Malam Ibrahim, ni ki i ṣe tulaasi rara lati jokoo ti ọkunrin ti ko ba sifẹẹ laarin wọn mọ, ati pe ofin Islam kan ti wọn n pe ni ‘Khuli’ faaye gba a pe ki obinrin jawee ikọsilẹ fun ọkọ rẹ, iyẹn ti ko ba ti nifẹẹ rẹ mọ gẹgẹ bii ohun ti Rahinat sọ nile-ẹjọ naa bayii.
Ṣa o, Ọgbeni Aliyu ti i ṣe ọkọ iyawo ni ẹgbẹrun mẹwaa Naira loun san dipo ẹgbẹrun marun-un ti iyawo oun sọ lowo ori Rahinat fawọn obi rẹ. O ni oun ko ṣetan lati gba owo ọhun pada lọwọ rẹ, ṣugbọn oun gba ki Rahinat kọ oun silẹ gẹgẹ bii ohun to n beere fun nile-ẹjọ naa.
Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Adajọ ile-ẹjọ naa, Malam Ibrahim, ni niwọn igba ti ọkọ iyawo ti yọnda iyawo rẹ pe ko maa lọ, ọrọ ko ruju mọ rara niyẹn. O paṣẹ fun Rahinat pe ko faaye oṣu mẹta gbako silẹ lẹyin toun ti tu wọn ka yii ko too fẹ ọkunrin mi-in gẹgẹ bii ofin Islam, eyi ti wọn n pe ni ‘Iddah’.