Faith Adebọla
Gẹrẹ ti wọn kede rẹ gẹgẹ bii ẹni to gbegba oroke ninu eto idibo sipo gomina nipinlẹ Eko, Gomina Babajide Oluṣọla Sanwo-Olu, ti dẹrin-in pẹẹkẹ awọn oṣiṣẹ pẹlu bo ṣe kede ẹkunwo ida ogun ninu ọgọrun-un owo-oṣu awọn oṣiṣẹ ọba ipinlẹ naa.
Ọjọ Aje, Mọnde, ogunjọ, oṣu Kẹta yii, ni ijọba Eko fi ikede naa lede nipasẹ lẹta kan ti olori awọn oṣiṣẹ ọba ipinlẹ Eko, Ọgbẹni Hakeem Muri-Okunọla, buwọ lu, lorukọ gomina.
O ni ẹkunwo naa kan gbogbo awọn oṣiṣẹ ọba bii awọn kọmiṣanna, darẹkitọ lawọn ẹka ileeṣẹ ọba, ati gbogbo awọn ọmọ-abẹ, titi dori oṣiṣẹ to n gba owo-oṣu to kere ju lọ.
Ẹkunwo naa tun de ọdọ awọn oloṣelu nijọba ibilẹ atawọn oṣiṣẹ lawọn kansu gbogbo, o kari ẹka eto idajọ, awọn oṣiṣẹ ileewosan, awọn tiṣa nileewe pamari, sẹkọndiri ati titi lọọ de fasiti, atawọn ajọ to n boju to ọrọ wọn, bẹẹ lẹkunwo ọhun ko yọ awọn oṣiṣẹ ileegbimọ aṣofin Eko, atawọn ẹka eto aabo, titi kan awọn to n ri si igbokegbodo irinna silẹ.
Ohun ti eyi tumọ si ni pe oṣiṣẹ to ti n gba ẹgbẹrun mẹwaa Naira owo-oṣu tẹlẹ yoo bẹrẹ si i gba ẹgbẹrun mejila, nigba ti eyi to ti n gba ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un yoo maa gba ẹgbẹrun lọna ọgọfa bayii, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ohun to tun mu kọrọ naa dun, ti gbọn-gbọn kan si i ni pe Sanwo-Olu ni ẹkunwo naa ti bẹrẹ lati oṣu Kin-in-ni, ọdun 2023 yii. O ni awọn maa san ẹkunwo to yẹ ko gori owo-oṣu Kin-in-ni, nigba tawọn ba n sanwo-oṣu Kẹta, nigba tawọn yoo san ẹkunwo ti oṣu Keji papọ pẹlu owo-oṣu Kẹrin, lẹyin eyi, ko ni i si ajẹsilẹ owo-oṣu kankan mọ.
O waa rọ awọn oṣiṣẹ ọba lati tubọ tẹpa mọṣẹ, ki wọn si fọwọ sowọ pọ pẹlu ijọba oun, tori tawo ba ki fun ni, niṣe la a ki fawo pada, ati pe beegun ẹni ba jo ire, ori aa ya atọkun ni.
Tẹ o ba gbagbe, oru ọjọ Aje, Mọnde, ogunjọ, oṣu yii, ni wọn kede Sanwo-Olu gẹgẹ bii ẹni to wọle ibo sipo gomina Eko. Lara orin ati aṣa tawọn alatilẹyin rẹ kọ fun un lasiko ti wọn n dawọ idunnu oriire naa ni pe ‘Sanwo-Olu tiwa, Sanwo-Eko tiwa.’