Laarin oru mọju oni ni ile ọkunrin ajijagbara, Sunday Adeyẹmọ ti wọn n pe ni Sunday Igboho, jona ni adugbo Soka niluu Ibadan. Ile naa jẹ ile ti Igboho n gbe tẹlẹ ko too ko lọ si ile rẹ tuntun.
Laarin oru, ni bii aago mẹta ni won sọ pe ina naa bẹrẹ, ko si sẹni to ti i sọ pe ohun to fa a niyi. Ina naa n jo lalaalaa, nigba ti awọn panapana yoo si fi de, ile naa ti jo jinna gan-an ni. Ẹgbẹ kan ti ina naa ti le ju jo kanlẹ, awọn panapana o si ri nnkan pa nibẹ nigba ti wọn de.
Sunday Igboho ni ẹni to fun awọn Fulani ni ọjọ meje ki wọn fi kuro ni ilu Igangan, nigba ti ọjọ to si da fun wọn pe, o ko awọn ọmọ rẹ lẹyin, wọn si le Seriki awọn Fulani, Salihu Abdukadri, to n ṣagidi nibẹ, oun ati awọn Fulani to ku, jade. Ọrọ naa di ariwo, ariwo naa si ṣẹṣẹ n lọ silẹ bayii ni ile ọkunrin naa tun jona. Wọn ko ti i sọ ohun to fa idi ina naa o.