Florence Babaṣọla
Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti tẹ obinrin alagbo kan, Ganiyat Ọladapọ, lori ẹsun pe o ta ọmọ ọlọmọ lẹgbẹrun lọna aadọjọ naira (#150,000).
Ganiyat, ẹni ọdun mejidinlogoji, la gbọ pe oun ati awọn kan ti wọn jọ n ṣiṣẹ buburu naa huwa ọhun ninu oṣu kẹfa ọdun to kọja.
Agbefọba to gbe olujẹjọ wa si kootu, Jacob Akintunde, ṣalaye pe ṣe ni wọn tan Mariam Ọladapọ lọ si ipinlẹ Anambra lati ilu Oṣogbo, nigba ti wọn debẹ ni wọn gba ọmọ to gbe lọwọ, ti wọn si ta a nibẹ.
Nigba ti wọn pada de, ti ko si si ọmọ lọwọ Mariam mọ, lawọn kan kọ ọ lati fọrọ naa to awọn agbofinro leti, ti ọwọ fi tẹ Iya alagbo.
Akintunde sọ siwaju pe iwa ti olujẹjọ hu lodi, bẹẹ lo si nijiya labẹ abala ikẹrinla ofin tita eeyan soko ẹru ti orileede yii n lo lati ọdun 2003.
Bi olujẹjọ ṣe sọ pe oun ko jẹbi ni agbẹjọro rẹ, Taiwo Awokunle, bẹbẹ fun beeli rẹ, o ni ko ni i sa lọ fun igbẹjọ.
Majisreeti Modupẹ Awodele fun un ni beeli pẹlu miliọnu kan naira (N1m) ati oniduro meji ni iye kan naa. O si sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kẹsan-an oṣu keji ọdun yii.