L’Ọṣun, awọn janduku pa Qudus, wọn tun dana sun aafin 

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Wahala nla lo bẹ silẹ niluu Ọ̀kánlà, nijọba ibilẹ Irẹpọdun, nipinlẹ Ọṣun, lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, nigba ti awọn janduku ti wọn dihamọra ogun ya bo aafin Ọlọkanla, ti wọn si pa ọmọkunrin kan, Ibrahim Qudus.

Qudus yii n mura lati wọ ileewe giga ni, lati ilu Ibadan lo si ti wa si Ọkanla laipẹ yii, ki wọn too da ẹmi rẹ legbodo. Lẹyin ti wọn pa a tan ni wọn tun dana sun aafin naa.

Ẹgbọn oloogbe, Jimoh Quadri, ṣalaye pe awọn janduku naa ni ọkunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Naim, ko sodi lọ sibẹ, oun nikan ni ko si da aṣọ boju laarin wọn.

Quadri, ẹni to sọ pe oun ko mọ idi ti awọn eeyan yii fi pa Qudus, ṣalaye pe wọn ti kọkọ wa oun wa sile, ṣugbọn wọn ko ba oun ko too di pe wọn lọ sile ti baba oun to ti doloogbe, Ọba Jimoh Adigun, lo gẹgẹ bii aafin Ọlọkanla ti Ọkanla nigba aye rẹ.

O ni, “Mi o si nile, ṣugbọn iyawo mi lo pe mi lori foonu pe awọn janduku ti wọn ko ibọn lọwọ, ti wọn si to ogun (20) wa si ile mi nidaaji Sannde. O sọ fun mi pe gbogbo wọn da aṣọ boju, ṣugbọn Naim ko da aṣọ boju ni tiẹ, wọn si wa gbogbo ayika ile boya wọn maa ri mi.

“Nigba ti wọn ko ri mi, wọn ba ile mi jẹ, ki wọn too kọja si ile mọlẹbi wa ti baba mi, Ọlọkanla ti Ọkanla, lo bii aafin. Nibẹ ni wọn ti ba Qudus, ọmọ ẹgbọn mi to n gbe n’Ibadan, aipẹ yii lo wa sile lẹyin to ṣedanwo UTME.

“Wọn pa a, wọn gbe oku ẹ sinu mọto mi to wa ninu ọgba aafin, wọn si dana sun mọto, lẹyin eyi ni wọn tun dana sun aafin. Mi o mọ idi ti wọn fi huwa naa, ṣugbọn o le jẹ nitori wahala ọrọ ilẹ to n lọ lọwọ lagbegbe wa ni. A waa n ke si awọn agbofinro lati ṣiṣẹ wọn bii iṣẹ, ki wọn wa awọn ti wọn huwa yii jade.”

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, sọ pe Kọmiṣanna ọlọpaa, Kẹhinde Longẹ, ti ṣabẹwo sibi iṣẹlẹ naa, o si ti da awọn ọlọpaa sagbegbe naa.

Amọ ṣa, Gomina ipinlẹ Ọṣun, Sẹnetọ Ademọla Adeleke ti paṣẹ konilegbele niluu Ifọn ati ilu Ilobu, aarin ilu mejeeji yii ni ilu Ọkanla wa.

Gẹgẹ bi atẹjade ti Kọmiṣanna feto iroyin, Amofin Kọlapọ Alimi, fi sita, o ni gomina ti paṣẹ pe ẹnikẹni ko gbọdọ rin tabi gbe mọto kọja lagbegbe naa laarin aago mẹjọ alẹ si mẹfa aarọ.

O ni ẹnikẹni to ba tasẹ agẹrẹ si ofin naa yoo fimu danrin, ati pe ki alaafia le jọba lagbegbe ọhun lo mu kijọba gbe igbesẹ naa.

Leave a Reply