L’Ọṣun, oṣiṣẹ aṣọbode, iyawo atawọn ọmọ ẹ mẹrin jona mọle

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Oṣiṣẹ aṣọbode kan ni ẹka ileeṣẹ naa nipinlẹ Ọyọ ati Ọṣun, Tijani Kabiru, loun atiyawo atawọn ọmọ rẹ mẹrin ti jona mọnu ile wọn niluu Ẹdẹ, nipinlẹ Ọṣun.

Iṣẹlẹ naa la gbọ pe o ṣẹlẹ nidaaji ọjọ Aje, Mọnnde, ọjọ keji, oṣu Kejila, ọdun yii, ninu ile wọn to wa ni Àkánkánm niluu Ẹdẹ, eleyii to si da ibanujẹ silẹ lagbegbe naa.

Bo tilẹ jẹ pe iyalẹnu iṣẹlẹ naa ko jẹ ki ọpọ awọn araadugbo naa le sọrọ lori rẹ, sibẹ, ẹnikan to pe ara rẹ ni Kọlawọle ṣalaye pe ni nnkan bii aago mẹta idaji ni eefin ru jade latinu ile ọhun.

O ni bi awọn araadugbo ṣe kẹẹfin efin ọhun ni wọn ke si ileeṣẹ panapana niluu Ẹdẹ, ṣugbọn ile naa ti jona kọjaa sisọ ki awọn panapana too de, Kabiru, iyawo atawọn ọmọ rẹ mẹrin si ti jona kọja aala.

Ọkunrin yii fi kun ọrọ rẹ pe ọkan ṣoṣo lara awọn ọmọ ọkunrin naa lo raaye sa jade ko too di pe ijamba ina ọhun ṣeku pa awọn to ku.

Ninu atẹjade kan ti Alakooso fun ileeṣẹ panapana nipinlẹ Ọṣun, Ọgbẹni Ọlaniyi Alimi, fi sita nipasẹ agbẹnusọ ileeṣẹ ọhun, Ibraheem Adekunle, o ni eeyan mẹfa lo padanu ẹmi wọn ninu ijamba ina ọhun.

O ṣalaye pe ni nnkan bii aago mẹta aabọ idaji ọjọ Aje, Mọnnde, ni awọn araalu pe ileeṣẹ naa lori nọmba ẹrọ ibanisọrọ pajawiri wọn, iyẹn, 08030808254, awọn ko si fi ọrọ naa falẹ rara, koda awọn tun pe awọn ti wọn wa ni Abere, lati waa ran wọn lọwọ.

Alimi fi kun ọrọ rẹ pe orukọ ọkunrin aṣọbode to doloogbe naa ni wọn fi sọri agbegbe to n gbe ni Custom Tijani Kabiru Road, Akankan Area, ijọba ibilẹ Ariwa Ẹdẹ.

O sọ siwaju pe Kabiru ti fẹẹ to ọmọ aadọta ọdun, nigba ti iyawo rẹ ti le diẹ ni ogoji ọdun, awọn ọmọ mẹrẹẹrin ti wọn ku sinu ijamba ina ọhun; ọkunrin mẹta ati obinrin kan, wa laarin ọdun mẹta si mẹwaa, nigba ti ọmọ to raaye sa jade jẹ ọmọ ọdun mẹtala.

Gẹgẹ bo ṣe wi, dukia to jona to miliọnu lọna igba Naira, nigba ti dukia ti ajọ panapana ri ko jade to miliọnu lọna ẹẹdẹgbẹta Naira.

O ni awọn ti ko awọn to doloogbe naa fun ileeṣẹ ọlọpaa A’ Division, niluu Ẹdẹ.

Leave a Reply