Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Irọ ni abi ootọ lo gbẹnu ọpọ olugbe ipinlẹ Kwara lalẹ ọjọ Aiku, Sannde, ọṣẹ yii, nigba ti wọn kede iku Alukoro ẹgbẹ PDP nipinlẹ naa, Ọgbẹni Tunde Ashaolu, ti wọn lo ku lọjọ keji to ṣayẹyẹ ayajọ ọjọọbi aadọta ọdun to dele aye.
ALAROYE, gbọ pe lọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ yii, ni ọkunrin naa dawọọ idunnu, to n yayọ ọjọ ibi, kọda, gbogbo fọto ibi ti oun pẹlu olori ileegbimọ aṣofin agba tẹlẹ, Sẹnetọ Bukọla Saraki, jọ ya, ti wọn si ge akara oyinbo niluu Abuja, lo gba gbogbo ori ayelujara lọjọ Abamẹta yii. Eyi lo mu ki awọn eeyan maa wo o pe iroyin ofege ni wọn n gbe kiri, bi o tilẹ jẹ pe titi di igba ti ALAROYE pari kiko iroyin yii jọ, wọn o ti i sọ pato iru iku to pa a, ṣugbọn wọn ilu Abuja, lo ku si.
Gbogbo awọn lookọ lookọ, awọn lẹgbẹ-lẹgbẹ, awọn oloṣelu ẹgbẹ rẹ, to fi mọ ẹgbẹ to n ṣejọba lọwọ ni Kwara, ni wọn ti n fi ọrọ ibanikẹdun ranṣẹ si mọlẹbi oloogbe.