London ni Olugbenga n lọ, ṣugbọn ọwọ awọn apaniṣowo lo bọ si  

Lọla Ojo

Aja to rele ẹkun to bọ, afi ka ki i ku oriire ni ọrọ baale ile kan, Maxwell Olugbenga Ajayi, to wọ mọto lati Oṣhodi, papakọ ofurufu Murtala Muhammed, to wa n’Ikẹja, lo n lọ o, o fẹẹ lọọ wọ baaluu ti yoo gbe e lọ si London, ni United Kingdom, ṣugbọn ọkunrin naa ko de papakọ ofurufu, bẹẹ ni ko de London, ojubọ awọn afiniṣowo lo ti pada ba ara rẹ niluu Ẹpẹ, ki ori too ko o yọ, nitori pe ẹlẹdaa rẹ ko gbabọde ibi.

ALAROYE gbọ pe ọkọ ofurufu Ethiopia lo yẹ ko ba lọ ni aago meji ku ogun iṣẹju ọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii, ko si balẹ si London ni deede aago meje ku iṣẹju mẹẹẹdọgbọn laaarọ ọjọ keji.

Ṣugbọn ọjọ Ẹti, Furaidee, to yẹ ko gbera ni wọn ji ọkunrin naa gbe ninu mọto to wọ.

Gẹgẹ bi ọkunrin ẹni ogoji ọdun naa ṣe ṣalaye iriri rẹ fun akọroyin Vanguard, o ni oun wọ ọkọ ero ni o, ṣugbọn niṣe ni gbogbo awọn to wa ninu ọkọ ọhun sun lọ fọnfọn lẹyin ti wọn fa oorun pafuumu kan ti kọndọkitọ mọto naa fin sinu ọkọ ọhun.

Ọkunrin yii ni oun ti kọkọ fi atẹranṣẹ ranṣẹ si ẹni to ba oun ṣeto irinajo naa, iyẹn awọn to n baayan ra tikẹẹti, toun si sọ fun un pe Uber loun feẹ gbe, ṣugbọn nitori pe dẹrẹba Uber naa sọ pe oun ko ni i ka mita foun, owo loun maa gba nitori sun-kẹrẹ-fa-kẹrẹ to wa loju ọna loun ko fi wọ ọ mọ.

O ni, ‘‘Bi mo ṣe lọọ wọ bọọsi to n lọ si Oshodi niyẹn, ṣugbọn lẹyin ti kọndọkitọ naa fin pafuumu sinu mọto, niṣe ni gbogbo wa sun lọ fọnfọn.

‘‘Nigba ti mo maa taji, ile to rẹwa daradara kan ni emi pẹlu gbogbo awọn ta a jọ wọ ọkọ naa ti ba ara wa, niṣe ni a n rin tagetage, a ko lokun ninu mọ rara, bẹẹ la si ri nnkan funfun kan lara wa.

‘‘Mo waa gbọ ti baba arugbo kan n sọ nibẹ pe ki wọn da emi ati ọkunrin kan silẹ ka maa lọ, o ni a ko wulo fun etutu ti awọn fẹẹ lo wa fun. Loju-ẹsẹ ni wọn ja oogun ti wọn so mọ wa lori, ni wọn ba ko wa sinu ọkọ, ni wọn ba wa wa lọ. Nigba ta a laju la ri i pe ilu Ẹpẹ ni ibi ti wọn ja wa ju silẹ si’.

Ọkunrin naa ni gbogbo awọn ti wọn ko lọ yii ni wọn ti wọ aṣọ dudu fun, ti wọn si n gbe igba le awọn lori lọkọọkan, o ni ti oogun naa ba ṣiṣẹ, wọn yoo mu ẹni ti wọn gbe igba le lori yii lọ, ṣugbọn ti ko ba ṣiṣẹ, wọn maa yọ ọ sẹyin.

Bayii ni Ọlọrun ko ọkunrin yii yọ lọwọ awọn apaniṣowo. Bi ko ba jẹ Ọlọrun to yọ ọ ni, awọn mọlẹbi re iba si wa nibi ti won ti n wa a kiri, wọn ko ni i mọ pe wọn ti fi i ṣe etutu.

 

Leave a Reply