Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ijọba ipinlẹ Ondo ti sọrọ lori awuyewuye to n ja ran-in-ran-in nilẹ lori ipo ti ilera Gomina Rotimi Akeredolu wa lọwọlọwọ.
Akọwe iroyin fun gomina, Richard Ọlatunde, ṣalaye ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ sawọn oniroyin lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, pe loootọ ni Aketi n ṣaisan, ṣugbọn ailera naa ki i ṣe eyi to lagbara to ariwo tawọn eeyan kan n pa kiri.
Ọlatunde ni ọpọlọpọ awọn eeyan ni wọn ti n pe lori ọrọ ilera Arakunrin Rotimi Akeredolu lati igba tọrọ ọhun ti jade sori ẹrọ ayelujara.
O ni idi ree ti oun fi ni lati tete sọrọ sita ki awọn araalu le fọkan ara wọn balẹ pe ko sewu kankan lori ilera gomina ọmọ bibi ilu Ọwọ ọhun rara.
O ni ki i ṣe tuntun rara pe Aketi n ṣaisan, nitori ọkunrin naa ki i ṣe angẹli tabi anjannu, eeyan ẹlẹran-ara bii tawọn ẹda yooku lasan ni, fun idi eyi, iroyin ailera Aketi ko yẹ ko jẹ ohun iyanu fawọn ara ipinlẹ Ondo, bẹẹ ni ki i sohun to yẹ ki wọn maa wo bii nnkan ajeji.
O ni loootọ lawọn eeyan to n ri Arakunrin le ṣakiyesi ailera rẹ latari ríru to ru hanngogo, amọ aisan to n ṣe e ko di i lọwọ lati ṣe awọn iṣẹ ilu to yẹ ko ṣe nitori pe oun lo ṣi dari ipade oloṣooṣu ti igbimọ iṣejọba ipinlẹ Ondo ati tawọn ẹṣọ alaabo, eyi to waye l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kọkanla, oṣu ta a wa yii.
Ninu ipade ọhun lo ni wọn ti jiroro lori rogbodiyan to n waye niluu Ikarẹ Akoko, ti wọn si gbe igbesẹ lori rẹ.
O ni ọpọ awọn eeyan ni wọn tun foju ara wọn ri Akeredolu nigba ti oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), Aṣiwaju Bọla Tinubu ṣaaju ikọ ipolongo rẹ wa siluu Akurẹ lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ keje, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii, kan naa. Ọjọ keji ti i ṣe ọjọ Aiku, Sannde, iyẹn ọjọ kẹjọ, oṣu Kin-in-ni, lo ni oun atawọn ọmọ igbimọ rẹ kan tun lọọ jọsin ninu ijọ Ridiimu nla to wa lagbegbe Oke-Ijẹbu, l’Akurẹ, fun eto isin iranti awọn ọmọ ogun to ti sun loju ija.
Ọjọ Ẹti, Furaide, ọsẹ to kọja, lo ni ọga oun tun lọọ ba awọn ẹgbẹ alapata, ẹka ti ipinlẹ Ondo, ṣe ifilọlẹ ọkọ amu-nnkan-tutu ti wọn ṣẹṣẹ ra.
Ọlatunde ni gbogbo ẹnu loun fi n sọ ọ pe aisan to n ṣe ọga oun ki i sohun le gẹ́gẹ́ bii ahesọ to n lọ nigboro nitori ko ṣee ṣe fun ẹnikẹni to ba wa lori idubulẹ aisan ti ko le dide lati ṣe awọn ohun ti oun ka soke wọnyi.
O rọ awọn eeyan ipinlẹ Ondo lati tubọ fọkan ara wọn balẹ pẹlu bi Gomina Akeredolu ṣe tun ṣetan lati tẹsiwaju ninu iṣẹ ribiribi to n ṣe lẹyin to ba ti wa akoko lati sinmi daadaa.
Tẹ o ba gbagbe, ọsẹ yii ni ariwo deede gba igboro lori fọnran kan ti iyawo rẹ, Arabinrin Betty Akeredolu, ti pariwo pe obinrin kan to n jẹ Bunmi Ademosun n waa fun ọkọ oun ni awọn agbo kan mu lori aisan to n ṣe e, eyi ti obinrin naa ni oun ko gbagbọ ninu rẹ.
Eyi lo jẹ ki ọpọ mọ pe o rẹ gomina naa diẹ, to si ko ipaya ba awọn ololufẹ rẹ ti wọn n pe e lọ pe e bọ lati mọ ipo ti ilera rẹ wa.