Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ọlanrewaju Adebayọ, ẹni ọdun mejilelọgbọn, ko fi bo pe oun ba ọmọ ọdun mẹjọ kan lo pọ lagbegbe Abule Iroko, ni Sango, loṣu to kọja, ohun to loun ko ṣe ni ti oogun owo ti wọn lo fẹẹ fọmọ naa ṣe.
Nigba to n ṣalaye ara ẹ f’ALAROYE lọjọ Aje Mọnde oni, ohun to sọ ni pe iṣẹ wolii loun n ṣe, oun si maa n jo nnkan nina daadaa. O ni awọn obi ọmọ naa lo pe oun pe koun waa ba wọn ṣe oogun aanu, oogun naa loun ṣe tan ti wọn tun ni koun ṣe fun ọmọ wọn obinrin to jẹ ọmọ ọdun mẹjọ, boun ṣe ni kọmọ naa tẹle oun lọ sile oun niyẹn, nitori ohun toun fi ṣiṣe naa fun wọn nile wọn ti tan, ile oun leyi to ku wa.
Ọkunrin yii sọ pe boun ṣe mu un dele loun sun le e lori, oun ba a laṣepọ, bo tilẹ jẹ pe ẹjẹ kankan ko jade bi ọmọ naa ṣe kere to.
Lori ikoko asejẹ ti wọn lo fi gbe asejẹ fọmọ naa, afurasi yii loun gbe e fun un loootọ, ṣugbọn ki i ṣe pe oun fẹẹ fi ọmọ naa ṣoogun owo bawọn obi ẹ ṣe n sọ.
Iya ọmọ naa ba ALAROYE sọrọ, Abilekọ Bọla Saidi lorukọ ẹ. O ṣalaye pe ọmuti kan ni Ọlanrewaju, o maa n tọrọ owo kiri ni bo tilẹ jẹ pe o maa n riran sawọn eeyan pẹlu iṣẹ wolii to n ṣe.
Iran kan lo ni o ri soun to fi di pe o wa oun wa sile, to ba ọkọ oun naa sọrọ, bo ṣaa ṣe ni koun jẹ ki ọmọ kekere naa tẹle oun dele niyẹn, lo ba mu ọmọ lọ lati aago mẹjọ aabọ aarọ, ti aago meji ọsan si fi lu, ọmọ naa ko pada wale.
”Mo wa ọmọ mi lọ sile ẹ, niṣe lo tilẹkun pa, awọn araale lo ba mi kanlẹkun ko too si i. Bi mo ṣe ba ọmọ mi nilẹẹ to n jẹ asejẹ niyẹn. Mo binu si i foun to ṣe naa, o si ni ki n ma binu.
”Nigba ta a n lọ lọmọ loun fẹẹ tọ, lo ba tun ni abẹ n ta oun, nigba ti mo wo abẹ ẹ ni mo ri ẹjẹ nibẹ, bi mo ṣe sare mu un pada sọdọ Eeso(Ọlanrewaju) niyẹn.
”Awọn eeyan lo ṣaa ba mi da si i to fi di ti ọlọpaa, ṣugbọn gbogbo ayẹwo ti wọn ṣe fọmọ mi lo fidi ẹ mulẹ pe o ti gba ibale ẹ, inu de tun n run ọmọ mi latigba naa, ohun to jẹ ka maa sọ pe o ti lo o niyẹn.’’
Ṣa, ọrọ yii n lọ si kootu laipẹ, nibi ti wọn yoo ti dajọ Ọlanrewaju to ba ọmọ ọdun mẹjọ lo pọ.