Adewale Adeoye
Ni bayii, ikọ eto iroyin ẹgbẹ oṣelu LP atawọn ololufẹ Peter Obi to dije dupo aarẹ ilẹ yii ninu eto idibo to waye lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keji, ọdun yii, ti sọ pe loootọ ni awọn ọlọpaa papakọ ofurufu ‘Heathrow’, niluu London, fọwọ ofin mu Peter Obi, ni gbara to de si papakọ ofurufu naa lati lọọ ṣe ayẹye ọdun Ajinde to kọja yii.
Ẹsun pe wọn n lorukọ rẹ lati maa fi ṣe awọn nnkan ti ko daa ni wọn ka si i lẹsẹ. Wọn ni lọjọ Ẹti, Furaidee, ti i ṣe ọjọ keje, oṣu Kerin, ọdun yii, ni Peter Obi de silẹ naa lati lọọ ṣe ayẹyẹ ọdun Ajinde pẹlu awọn ẹbi rẹ lọhun-un, ṣugbon to jẹ pe loju-ẹsẹ lawọn ọlọpaa to wa ni papakọ ofurufu ọhun ti mu un jade laarin ọpo ero, nibi ti wọn ti sọ fun un pe o lẹjọ lati jẹ lọdọ awọn.
Ṣe la gbọ pe ẹnu ya ọpọ awọn ero to wa nibẹ nitori pe ki i ṣe igba akọkọ ree ti Peter Obi maa lọ si London, ko too di pe wọn tun fẹsun ti ko lẹsẹ nile kan an. Nigba ti wọn ko tete ju u silẹ, ti oju awọn ọmọ orile-ede yii kọọkan ti wọn wa nibẹ lọjọ naa ko gba a mọ ni wọn ba n kigbe lati fẹhonu han tako ọwọ lile ti wọn fi mu ọrọ Peter Obi.
Ko si pẹ rara lẹyin tawọn ero n pariwo tawọn ọlọpaa ọhun fi ju u silẹ pe ko maa lọ layọ ati alafiaa.
Alukoro eto ipolongo ibo fun Peter Obi, Ọgbẹni Diran Onifade ni, ‘‘Ki i kuku ṣe pe Peter Obi jẹ ajoji rara nilẹ naa, o ti di gbajumọ daadaa lorilẹ-ede yii ati ni agbaye, paapaa ju lọ bo ti ṣe jẹ pe oun lo ṣe ipo kẹta ninu awọn bii mejidinlogun ti wọn jọọ dupo aarẹ ilẹ yii laipẹ yii.
‘‘Gbara ti wọn ti fọwọ lile mu Obi ni papakọ ofurufu ọhun, tawọn eeyan si n reti pe ki wọn fi i silẹ ti wọn ko tete fi i silẹ lo mu ki awọn ololufẹ rẹ ti wọn wa nibẹ fi ẹhonu han, ẹnu si ya awọn ọlọpaa to n ṣewadii nipa ẹsun ti wọn fi kan an, loju-ẹṣe ni wọn si ti waa ba awọn ero ọhun sọrọ ati idi ti wọn ṣe n fọrọ wa a lẹnu wo.
Wọn ni ṣe lẹnikan n forukọ rẹ lu jibiti kaakiri ilu, to si ṣe pataki fun awọn lati ṣewadii daadaa nipa ohun to n ṣẹlẹ naa, kawọn baa le mọ ọna tawọn maa gba mu oniṣẹ ibi naa.
Alukoro ọhun ni latigba ti wọn ti pari ibo aarẹ ilẹ yii tan ni awọn kọọkan ti n wa ọna lati ba orukọ daadaa Peter Obi jẹ pẹlu bi wọn ṣe n da ọgbọn loriṣiiriṣii lati ka awọn ẹsun ti ko lẹsẹ nilẹ si i lẹsẹ nigba gbogbo. Lara iru rẹ tun ni bi awọn kan tun ṣe n lọọ forukọ rẹ lu jibiti bayii loke okun, to fi jẹ pe awọn ọlọpaa Oke Okun waa n fọwọ lile mu un bayii.
Gbogbo ọna ni wọn n wa lati ba a lorukọ jẹ, gbara ti eto idibo ọhun ti pari tan ni awọn alaṣẹ ilẹ yii ti sọ pe ki ẹni ti esi ibo naa ko ba tẹ lọrun rara gba ile-ẹjọ lọ, awọn kan naa ni wọn tun ran minisita eto iroyin ilẹ yii lọ soke okun lati maa sọ awọn ohun ti ko ṣẹlẹ nipa Peter Obi, wọn ṣaa n wa gbogbo ọna ni lati ba a lorukọ jẹ.
Nigba ti ko ṣee ṣe fun wọn ni awọn kan tun gba a nimọran pe ko lọọ fun ara rẹ nisinmi l’Oke-Okun, bẹẹ o ṣee ṣe ko jẹ pe wọn ti kẹ panpẹ de e pẹlu bawọn ọlọpaa ṣe daa duro lori ohun ti ko mọwọ mẹsẹ rara.