Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ẹgbẹ oṣelu Labour, ẹka ti ipinlẹ Ondo, ti wọ ajọ to n ṣeto idibo lorilẹ-ede ede yii (INEC), ẹgbẹ All Progressives Congress (APC), lọ sile-ẹjọ lori bi wọn ṣe yọ orukọ awọn oludije wọn bii ẹni yọ jiga kuro ninu iwe idibo sileegbimọ aṣoju-ṣofin ati aṣofin agba, eyi ti wọn di kọja.
Adari eto ipolongo fun ẹgbẹ oṣelu ọhun nipinlẹ Ondo, Ọmọwe Abiọdun Ambọde, lo fidi ọrọ yii mulẹ ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ sawọn oniroyin lopin ọsẹ to kọja.
Ambọde ni ohun ti ko bojumu rara ni bi orukọ awọn oludije awọn ṣe di awati ninu iwe idibo agbegbe Guusu Ila-Oorun /Guusu Iwọ-Oorun Akoko, Ila-Oorun /Iwọ-Oorun Ondo, Ariwa /Guusu Akurẹ, Irele/Okitipupa ati ẹkun Aarin Gbungbun Ondo, ninu eto idibo sileegbimọ aṣoju-ṣofin ati aṣofin agba l’Abuja, eyi to waye lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keji, ọdun yii.
O ni ajọ eleto idibo ati gbogbo awọn oludije to jawe olubori ninu eto idibo naa lawọn ti pe lẹjọ nipasẹ agbẹjọro awọn, Amofin Oluṣọla Ebiṣeni, latari ami ati orukọ ẹgbẹ awọn ti ko si lara iwe eto idibo ti wọn lo.
O ni igbesẹ ọhun lodi sofin eto idibo orilẹ-ede yii, eyi ti wọn ṣe atunṣe rẹ ni ọdun 2022, nitori lati ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹwaa, ọdun 2022, ni awọn ti kọ lẹta si ajọ naa, ninu eyi ti awọn to gbogbo orukọ awọn eeyan ti yoo dije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour si.