Lori ẹsun ikowojẹ, EFCC n wa Olu Agunloye 

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku lorilẹ-ede yii, Economic and Financial Crimes Commission ( EFCC), ti ni awọn n wa Dokita Olu Agunloye lati waa jẹjọ ẹsun ikowojẹ ati jibiti lilu ti wọn fi kan an.

Agunloye, to ti figba kan jẹ minisita fọrọ ileeṣẹ nnkan agbara lasiko ijọba Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ni ajọ EFCC kede orukọ rẹ pe awọn n wa loju opo Fesibuuku wọn lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejila, oṣu Kejila yii.

EFCC, ninu atẹjade ti wọn lẹ aworan oludije sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ Social Democratic Party, ninu eto idibo gomina to kọja nipinlẹ Ondo, mọ gbagadagbagada ọhun ni wọn ti ni awọn n wa a fun ẹsun iwa ibajẹ ati iwe yiyi.

Wọn ni ẹni ọdun marundinlọgọrin ni, to si wa lati ijọba ibilẹ Ariwa Akoko, nipinlẹ Ondo, Wọn ni Ojule ogun, Opoopona Sold Boney, n’Ibadan, ipinlẹ Ọyọ lawọn mọ pe o n gbe tẹlẹ.

Wọn rọ ẹnikẹni to ba ba awọn ri ọga awọn ẹṣọ oju popo tẹlẹ ri ọhun lati kan si ọfiisi wọn to wa ni Benin, Kaduna, Ibadan,  Sokoto, Maiduguri, Makurdi, Ilọrin, Enugu, Kano, Lagos, Gombe, Uyo, Port-Harcourt ati Abuja.

Agunloye ti kọkọ ṣẹ ẹsun yii lasiko to n dahun ibeere lati ọdọ awọn oniroyin ori ẹrọ ayelujara kan ninu oṣu Kẹsan-an, ọdun ta a wa ninu rẹ yii. O ni loootọ ni EFCC ti kọkọ fi pampẹ ofin gbe oun, ti wọn si fọrọ wa oun lẹnu wo laarin asiko diẹ, ti wọn fi ti oun mọle lọdọ wọn.

Ọkunrin yii ni ko ye oun rara bi EFCC ṣe n fọrọ iṣẹ akanṣe olowo nla Mambilla Hydropower, ṣe ẹni a le mu laa lẹdi mọ. O ni o jọ oun loju pupọ bi ajọ to ni oun n gbogun ti iwa ibajẹ naa ṣe fi awọn to yẹ ki wọn mu, ki wọn si wadii wọn daadaa lori ọrọ naa silẹ, to si waa jẹ oun gan-an ni wọn n wa kiri.

 

Leave a Reply