Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti
O jọ pe ija ko ti i pari rara lori bi ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) ati People’s Democratic Party (PDP) ṣe n ju ogulutu ọrọ sira wọn latari awọn igbesẹ tijọba to wa lode nipinlẹ Ekiti n gbe.
Eyi to n ja ran-in ran-in lọwọ ni gbọngan aṣa tijọba ipinlẹ naa ti fẹẹ kọ pari bayii tawọn aṣofin ni ki wọn sọ lorukọ Gomina Kayọde Fayẹmi, ṣugbọn ti ẹgbẹ oṣelu PDP ṣapejuwe gẹgẹ bii ainikan an ṣe.
Nibẹrẹ ọsẹ to kọja, iyẹn nigba tawọn aṣofin Ekiti n ṣayẹyẹ ọdun kan ti wọn bẹrẹ saa tuntun, ni wọn fẹnuko pe kijọba sọ orukọ gbọngan naa to wa lagbegbe Fajuyi, niluu Ado-Ekiti, lorukọ Fayẹmi, ẹni ti wọn lo ti ṣe awọn iṣẹ akanṣẹ manigbagbe kaakiri.
Ṣugbọn ẹgbẹ oṣelu PDP nipasẹ akọwe igbimọ oludari wọn nipinlẹ naa, Diran Ọdẹyẹmi, sọ pe igbesẹ ọhun fi han pe korofo lawọn aṣofin naa, bẹẹ ni imẹlẹ n da wọn laamu.
O ni ninu ọdun mẹfa ti Fayẹmi ti lo lori aleefa, eyi to jẹ apapọ saa kin-in-ni rẹ lọdun 2010 si 2014 ati eyi to bẹrẹ lọdun 2018, ko si nnkan to le tọka si bii aṣeyọri, to waa jẹ pe gbọngan ti wọn n kọ lọwọ lo tọ si i loju awọn aṣofin.
Ọdẹyẹmi ni biliọnu mẹta ti Fayẹmi ti na lori iṣẹ akanṣẹ naa lo yẹ kawọn aṣofin ṣewadii, bẹẹ lo yẹ kawọn eeyan yii beere nnkan to n ṣe lati ọdun 2012 ti wọn ti bẹrẹ si i kọ ile ọhun.
O waa ni biriiji ilu Ado-Ekiti jẹ iṣẹ akanṣe kan tawọn eeyan Ekiti ko le gbagbe nipa Ayọdele Fayoṣe to jẹ gomina ana ati ọmọ ẹgbẹ PDP, ṣugbọn ileeṣẹ Clay Kaolin to tiẹ wa niluu Fayẹmi, ko si nnkan to ṣe si i lasiko to jẹ minisita fun ohun alumọọni.
Nigba to n fesi lorukọ APC, Sam Oluwalana to jẹ adari ẹka iroyin sọ pe Ọdẹyẹmi ko mọ nipa ilọsiwaju Ekiti, igbesẹ tawọn aṣofin si gbe jẹ nnkan tawọn araalu ran wọn.
Oluwalana ṣalaye pe ilara ni ẹgbẹ oṣelu PDP n ṣe, ati pe Fayẹmi ko da bii Fayoṣe to fi ọja sọ orukọ ara ẹ lai tẹle ilana ofin nitori pe o lagbara ju awọn aṣofin lọ, titi de ori abẹnugan.
O waa fẹsun kan PDP pe ẹgbẹ wọn n ku lọ, wọn ko si wa atunṣe si i, ṣugbọn ṣe ni wọn n pariwo gomina to n ṣe daadaa kiri lati ba a lorukọ jẹ.
Titi di asiko ta a pari akojọpọ iroyin yii lẹgbẹ mejeeji ṣi n sọrọ sira wọn lori ipinnu awọn aṣofin yii, ko si sẹni to mọ ohun ti yoo gbẹyin awuyewuye naa.