Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Awọn ọmọ ẹgbẹ APC nipinlẹ Ekiti ti fẹsun ijẹgaba lori ẹni kan Gomina ipinlẹ naa, Ọmọwe Kayọde Fayẹmi. Wọn ni niṣe lo fẹẹ da nikan kọ orukọ awọn ọmọ ẹgbẹ naa ti yoo ṣoju wọọdu kọọkan ninu eto idibo awọn oloye ẹgbẹ to n bọ lọna.
Latari eyi, awọn ọmọ ẹgbẹ APC Ekiti ke si awọn oloye ẹgbẹ yii l’Abuja, paapaa awọn igbimọ fidiẹ-hẹ, pe ki wọn yee kawọ gbera, ki wọn ṣe ohun gbogbo to yẹ lati ri i pe Gomina Fayẹmi ko lo ọgbọn alumọkọrọyi lati fa awọn ti wọn yoo ṣoju ninu eto ibo awọn oloye ẹgbẹ kalẹ.
Aṣofin ana kan nipinlẹ Ekiti to tun jẹ ọkọ ọmọ Aṣiwaju APC l’Ekoo, Oloye Bọla Tinubu, iyẹn Ọnarebu Tunji Ojo, fi lẹta ẹhonu kan sita lori ọrọ yii.
Ninu lẹta naa to kọ lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii, to fi ṣọwọ sawọn oniroyin l’Ado-Ekiti, lo ti sọ pe Fayẹmi gan-an ni igi wọrọkọ ti i dana ru, oun lo n da omi alaafia ẹgbẹ APC ipinlẹ Ekiti ru.
Ọnarebu Ojo fi han pe ijọba Ekiti, labẹ akoso Dokita Kayọde Fayẹmi ti bẹrẹ igbesẹ lati kọ orukọ awọn ọmọ ẹgbẹ ti yoo lo lati wọọdu kọọkan titi de ijọba ibilẹ. O ṣalaye pe wọn ṣe eyi lati ri i pe wọn yan ẹni to ba wu wọn sori ipo lasiko ibo ni.
O fi kun alaye ẹ pe ijọba ipinlẹ Ekiti ti paṣẹ pe kawọn ọmọ ẹgbẹ ma ṣepade wọọdu mọ, tabi ipade mi-in ninu ẹgbẹ naa. Ojo sọ pe wọn ṣe eyi lati ri i pe awọn ọmọ ẹgbẹ ko sọrọ to jọ mọ idibo naa mọ, ki Fayẹmi le yan awọn to ba wu u sipo.
O ni igbesẹ ti gomina fẹẹ gbe yii ko daa fun ijọba Dẹmokiresi, bẹẹ lo si le fa a n gbe ara eni lọ sile-ẹjọ.
“A n fi asiko yii pe awọn igbimọ fidiẹ-ẹ atawọn oloye mi-in ninu ẹgbẹ APC, pe ki wọn jigiri si iwa aisootọ to n lọ lọwọ nipinlẹ Ekiti. Awa ọmọ ẹgbẹ ko ni i gba ki aisootọ mulẹ ninu ẹgbẹ wa.
“A ko ni i gba ki gomina kan to gba ẹtọ wa lọwọ wa ni 2014 tun gba a bayii, nitori oṣelu inira lo ko wa si’’ Bẹẹ ni aṣofin tẹlẹ yii wi.