Lori iku Mohbad: Ileeṣẹ ọlọpaa kede pe awọn n wa ọmọkunrin olorin yii

 Faith Adebọla

Pẹlu bi iwadii lọkan-o-jọkan ṣe n lọ lọwọ, ti ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko si ti ranṣẹ pe awọn kan lati waa sọ ohun ti wọn mọ nipa iku ọdọmọde olorin nni, Ilerioluwa Ọladimeji Alọba, wọn ti kede pe awọn n wa ọmọkunrin olorin kan torukọ rẹ n jẹ Owodunni Ibrahim, ti gbogbo eeyan mọ si Prime Boy. Miliọnu kan Naira ni awọn agbofinro lawọn yoo fun ẹnikẹni to ba mọ ibi ti ọmọkunrin naa wa, tabi to le ṣatọna bi awọn ṣe le ri i

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, Benjamin Hundeyin, lo sọrọ yii di mimọ ninu ọrọ kan to gbe si ori ikanni agbọrọkaye rẹ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹrin, oṣu Kẹwaa yii.

O ni, ‘‘Pẹlu bo ṣe kọ lati jẹ ipe wa lori iwe ipe ti a fi ranṣẹ si i lati yọju si ileeṣẹ wa latigba ti iwadii ti bẹrẹ lati tan imọlẹ si iku to pa Ilerioluwa Ọladimeji Alọba, ti gbogbo eeyan mọ si Mohbad, ileeṣẹ ọlọpaa kede lati akoko yii lọ pe a n wa Owodunni Ibrahim ti gbogbo eeyan mọ si Prime Boy’’.

Alukoro yii waa kede pe miliọnu kan Naira lawọn yoo fun ẹnikẹni to ba mọ ibi ti ọmọkunrin naa wa tabi to ba sọ bi awọn ṣe le ri i.

Tẹ o ba gbagbe, latigba ti iku aitọjọ ti pa Mohbad ni ariwo ti n lọ loriṣiiriṣii, ti awọn ọrẹ, mọlẹbi atawọn alatilẹyin rẹ si n pe fun idajọ ododo. Eyi lo fa a ti awọn ọlọpaa fi gbe igbimọ kan dide lati tanna wadii ọrọ naa.

Lara awọn ti ileeṣẹ ọlọpaa ti ranṣẹ si, ti wọn si ti jẹ ipe wọn lati waa sọ ohun ti wọn mọ nipa iku ọmọkunrin ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn naa ni Samson Ọladimeji ti gbogbo eeyan mọ si Sam Larry. Ọṣẹ to kọja ni ọmọkunrin to maa n tẹle Naira Marley, toun naa si n gbe awọn olorin jade yii de si Naijiria lati orileede Kenya to wa. Bẹẹ lawọn ọlọpaa si ti mu un si akata wọn.

Bakan naa ni Azees Fashọla, ti gbogbo eeyan mọ si Naira Marley, naa ti wa lakolo awọn ọlọpaa titi di ba a ṣe n sọ yii. Ọmọkunrin olorin to ti figba kan gbe awo orin Mohbad jade yii naa wa lara awọn ti ọlọpaa kọwe ranṣẹ si pe ko waa sọ ohun to mọ nipa iku oloogbe yii.

Leave a Reply