Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti
Ijọba ipinlẹ Ekiti ti tọrọ aforiji lori iṣẹlẹ to waye l’Ọjọru, Wẹsidee, ọsẹ yii, ninu eyi ti awọn oṣiṣẹ olowo-ori ti ti geeti ileewe alakọọbẹrẹ kan pa lasiko tawọn ọmọde wa nibẹ.
Iṣẹlẹ ọhun lo waye nileewe Adonai, to wa lagbegbe Baṣiri, niluu Ado-Ekiti, awọn oṣiṣẹ Ekiti State Internal Revenue Service lo si huwa ọhun, eyi to mu araalu binu gidigidi.
Ẹnikan to jẹ oṣiṣẹ ileewe naa sọ pe awọn olowo-ori ọhun ti geeti ileewe naa nitori wọn ni awọn jẹ owo, lasiko ti obinrin kan tọmọ ẹ n ṣaisan, to si fẹẹ sare gbe e lọ sileewe de lo too han pe awọn eeyan naa ko ṣetan lati ṣi geeti.
Eyi lo jẹ ki wọn ja agadagodo ti wọn fi ti i, ti wọn si gbe ọmọ naa jade, ṣugbọn awọn oṣiṣẹ ijọba yii tun pada ti i, lasiko naa si ni obi kan ya fidio to ṣakoba fawọn eeyan naa lẹyin to balẹ sori intanẹẹti.
Esi ijọba l’Ọjọbọ, Tọsidee, ni pe wọn ko ti ọmọ kankan mọ inu ọgba naa, nigba to si di ọjọ Ẹti ni wọn tọrọ aforiji, wọn ni awọn ṣe aṣiṣe.
Ninu atẹjade kan ti Kọmiṣanna feto iroyin, Ọnarebu Akin Ọmọle, fọwọ si lo ti ni ijọba tọrọ aforiji nitori awọn nnkan kan wa to yẹ kawọn ṣe tawọn ko ṣe.
O ṣalaye pe lati asiko naa lọ, ko si ileewe ti wọn yoo ti pa lasiko tawọn ọmọ ba wa nibẹ nitori ijọba ko ni i gba ki iya jẹ awọn ọmọde.
O waa kilọ pe oṣiṣẹ to ba huwa to jọ mọ ifiyajẹni yoo daran, bẹẹ ni ọrọ owo-ori ko ni i da iru wahala bẹẹ silẹ mọ latari bi ijọba ṣe mọ pe ọrọ-aje ko lọ deede fawọn onileewe nitori arun Koronafairọọsi.