Lori ọrọ ipo Imaamu, ijọba fẹẹ gbena woju Olukarẹ Ikarẹ Akoko

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ijọba ipinlẹ Ondo ti fa ibinu yọ si Olukarẹ tilu Ikarẹ Akoko, Ọba Akadiri Momoh, lori bo ṣe n gbe igbesẹ ati yan adele-imaamu agba fun mọsalasi gbogbogboo to wa niluu ọhun.

Adele Gomina ipinlẹ Ondo, Ọnarebu Lucky Orimisan Ayedatiwa, lo fi eyi han ninu lẹta kan to fi ṣọwọ si ọba alaye ọhun. O ni ijọba ti ṣetan lati rọ ọ loye to ba fi kuna lati yi ipinnu rẹ pada laarin wakati mẹrinlelogun pere.

Ayedatiwa ni igbesẹ yiyan adele imaamu agba lasiko tijọba ṣi n wa gbogbo ọna ti yoo fi yanju rogbodiyan to wa laarin awọn Musulumi ìlú Ikarẹ, ko le tun nnkan ṣe rara, bẹẹ ni ko ni i jẹ ki ọrọ ọhun loju, ati pe ṣe ni yoo tun maa dojuru si i.

O ni Ọba Momoh ti ja ireti ijọba kulẹ lori igbesẹ naa, nitori olori ìlu to ba n wa alaafia ati ki nnkan dara laarin ilu ko ni i ṣe bẹẹ láéláé.

Adele Gomina juwe iwa Olukarẹ yii bii nnkan itiju patapata, ti ijọba ko si ni i fojuure wo.

O ni Ọba Momoh gbọdọ tọrọ aforiji lọwọ ijọba kiakia fun iwa àfojúdi to hu naa, bẹẹ lo ni awọn ko fẹẹ ri ẹni to ṣẹṣẹ yan ọhun ko maa pe ara rẹ ni imaamu agba mọsalasi Ikarẹ láti asiko yii lọ.

Ijọba ni ko gbọdọ si ipejọpọ tabi ipade adura kankan lasiko yii ninu mọsalasi gbogbogboo Ikarẹ, bẹẹ ni wọn ko gbọdọ dabaa ati sadura ọdun Itunu Aawẹ to n bọ yii nibẹ.

Pariparí rẹ ni pe, ijọba loun ti fofin de Olukarẹ pe ko gbọdọ dabaa ati pe ipade kankan tabi ko awọn eeyan kankan jọ sinu aafin rẹ, nitori ohunkohun lasiko yii.

Ijọba paṣẹ fun Ọba Momoh lati ṣeto bi alafia yoo ṣe jọba ni gbogbo tibu-tooro ìlú Ikarẹ Akoko, wọn ni kabiyesi ni yoo fori ko o bi ohunkohun ba lọọ ṣẹlẹ to da àlàáfíà ilu ru.

 

 

Leave a Reply