Lori ọrọ Ọmọborty ti wọn lo gba ọkọ ọmọ mi, eyi ni b’ọrọ ṣe jẹ-Lọla Idijẹ

Ọrẹoluwa Adedeji

Arẹwa oṣere to maa n daṣa oriṣiiriṣii ninu ere nni, Toyin Afọlayan, ti gbogbo eeyan mọ si Lọla Idijẹ, ti sọrọ lori ohun tawọn kan sọ nipa rẹ, ti wọn si n gbe e kiri ori ayelujara. Laipẹ yii ni oṣere to niwaju atẹyin to daa nni, Biọdun Ọkẹowo, ti gbogbo eeyan mọ si Ọmọborty, jade sita, to si fi ẹdun ọkan rẹ han si ẹsun kan ti wọn fi kan an pe o fi owo ra ọkọ rẹ ni, ati pe nitori iwe igbeluu lo fi fẹ ọkọ to ṣẹṣẹ gbe e sile bayii.

Bakan naa ni wọn tun fẹsun kan an pe ọkọ to yẹ ki ọmọ agba oṣere nni, Lọla Idijẹ fẹ ni Biọdun fọgbọn gba lọwọ rẹ. Wọn ni nigba ti wọn fi ọmọkunrin naa han an lo fọgbọn gbe e mọra. Iroyin ayeluara kan lo gbe gbogbo ọrọ naa, ti Biọdun si jade lati fesi pe oun ko gba ọkọ ọlọkọ. Oṣere naa ni bo ba jẹ tori iwe igbeluu, owo wa lọwọ oun ti oun le fi ṣeto eleyii.

Latigba to ti sọrọ naa lawọn eeyan ti n reti ki Lọla Idijẹ sọrọ lori ẹsun ti wọn fi kan Ọmọborty.

Ni bayii, Idijẹ, bi wọn ṣe tun maa n pe obinrin naa ti jade sọrọ, ohun to si sọ ni pe Ọmọborty ko gba ọkọ ọmọ oun kankan gẹgẹ bi awọn eeyan ṣe n gbe e kiri. Lọla ni igba akọkọ ti oun maa mọ ọkọ Ọmọborty ni nigba to fi i han oun lori foonu nigba ti awọn jọ sọrọ. O ni oun ko mọ ọn nibikibi tẹlẹ.

O fi kun un pe ko si ẹnikẹni ninu awọn ọmọ oun to mọ ọmọkunrin naa, bẹẹ ni ko gba ọkọ ọmọ oun kankan. O ni to ba jẹ pe iru nnkan bẹẹ ṣẹlẹ, oun ko ni i lọ sibi igbeyawo rẹ ti oun lọ.

Pẹlu ohun ti Lọla Idijẹ sọ yii, ireti awọn eeyan ni pe opin yoo de ba ahesọ oriṣiiriṣii to gba ori ayelujara lori ọrọ naa, eyi ti ọpọlọpọ eeyan ti n gba bii ẹni gba igba ọti.

Bẹ o ba gbagbe, aipẹ yii ni Ọmọborty ṣegbeyawo pẹlu ọkunrin ara ilu Oyinbo kan.

 

Leave a Reply