Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti
Ẹgbẹ oṣelu People’s Democratic Party nipinlẹ Ekiti ti fẹsun kan Gomina Kayọde Fayẹmi pe o fẹẹ lu awọn oṣiṣẹ-fẹyinti ni jibiti ida mẹẹẹdogun owo ajẹmọnu wọn.
PDP ni ijọba fẹẹ gbe igbesẹ naa pẹlu ifọwọsowọpọ ileeṣẹ kan to wa niluu Eko, iyẹn United Capital PLC, biliọnu mẹfa naira ni wọn yoo si jọ pin lẹyin eto irẹnijẹ ọhun.
Akọwe igbimọ to n dari ẹgbẹ naa, Diran Ọdẹyẹmi, lo sọko ọrọ ọhun lopin ọsẹ to kọja pẹlu bo ṣe ni laipẹ nijọba yoo pin fọọmu fawọn oṣiṣẹ-fẹyinti, tipatipa ni wọn yoo si fi fọwọ si owo yiyọ naa.
Ọdẹyẹmi ṣalaye pe ni saa akọkọ Fayẹmi, biliọnu meje lo n gba loṣooṣu lọwọ ijọba apapọ, bẹẹ lo tun gba owo to le ni biliọnu mẹrindinlaaadọta naira (N46b) ninu ajẹṣẹku owo epo rọbi, ṣugbọn ko sanwo fawọn oṣiṣẹ-fẹyinti.
O ni Fayẹmi ti waa ṣetan lati ya owo, ko le sanwo fun wọn bayii, bẹẹ ni yoo yọ ida mẹẹẹdogun, eyi to tumọ si pe bo ṣe n gbowo lọwọ awọn kọngila to n yawo sanwo fun niyi.
Ọdẹyẹmi fi kun un pe lọdun 2018 ti Fayẹmi bẹrẹ saa keji, awọn adari ileeṣẹ ijọba to fẹyinti nikan lo fun ni miliọnu mejila si mẹẹẹdogun Naira ẹnikọọkan, bẹẹ ni wọn n gba ẹgbẹrin lọna irinwo naira (N400,000) loṣu, ṣugbọn ko sanwo fawọn ti ko gba to ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira.
O waa ni biliọnu mẹrin ni yoo bọ sapo Fayẹmi ninu biliọnu mẹfa to fẹẹ yọ bayii, akaunti oke okun kan ni yoo si ko o pamọ si.
Nigba to n fesi si awọn ẹsun wọnyi, Ọgbẹni Akin Oyebọde to jẹ ọkan lara awọn oludamọran pataki fun gomina ni gbese ti Fayẹmi jẹ silẹ pọ lori ọrọ awọn oṣiṣẹ-fẹyinti, o si ti san owo to le ni biliọnu kan ninu biliọnu mẹrinla.
O ni gomina n san miliọnu lọna ọgọrun-un loṣooṣu fun wọn, yatọ si miliọnu mẹwaa ti Fayoṣe n san, ṣugbọn ọrọ arun Koronafairọọsi ti mu nnkan nira, eyi lo jẹ kijọba lọọ ba ileeṣẹ kan fun iranlọwọ.
Oyebọde ni ileeṣẹ yii ni yoo ran ijọba lọwọ lati sanwo fawọn oṣiṣẹ-fẹyinti ti wọn ba fẹẹ gbowo wọn lẹẹkan, eyi ti yoo mu wọn san ida mẹẹẹdọgun, ṣugbọn awọn to ba fẹẹ maa gba owo wọn diẹdiẹ lọwọ ijọba yoo gba gbogbo ẹ.
O waa ni eyikeyii eto tawọn oṣiṣẹ-fẹyinti naa ba mu ni yoo ṣe wọn lanfaani, gbogbo wọn patapata ni yoo si kan.