Ọlawale Ajao, Ibadan
Oludije dupo gomina ninu idibo abẹle ẹgbẹ oṣelu All Progresives Congress, APC, Oloye Adebayọ Adelabu, ti kede pe oun ko ṣe ẹgbẹ oṣelu ọhun mọ.
Nigba to n kede ipinnu naa fawọn ololufẹ ẹ n’Ibadan nirọlẹ ọjọ Aiku, Sannde, to kọja, Oloye Adelabu sọ pe oun yoo papa dupo gomina ninu ẹgbẹ oṣelu mi-in, oun yoo si pada sinu ẹgbẹ oṣelu Onigbaalẹ nigba ti oun ba dibo wọle tan gẹgẹ bii gomina lẹyin idibo ọdun 2023.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Niwọn igba ti awọn alatilẹyin mi ti sọ pe ka fi ẹgbẹ APC silẹ, a ti kuro ninu ẹgbẹ APC bayii, ṣugbọn lẹyin ta a ba jokoo sọrọ pẹlu awọn agbaagba ẹgbẹ la too maa mọ inu ẹgbẹ oṣelu ta a maa lọ.
“Oloogbe Abiọla Ajimọbi gbe iru igbesẹ yii nigba ti wọn kuro ninu ẹgbẹ AC, ti wọn dara pọ mọ ẹgbẹ ANPP. Lati inu ẹgbẹ yẹn ni wọn ti pada sinu ẹgbẹ ACN. Igbesẹ yẹn ko si bu wọn lọwọ.
“A maa jẹ kẹ ẹ mọ inu ẹgbẹ tuntun ti a n lọ. Ẹyin ẹ fun wa lọjọ meji pere lati forikori pẹlu awọn agbaagba ẹgbẹ naa.
Tẹ o ba gbagbe, Oloye Adelabu lo wọle idibo abẹle ẹgbẹ oṣelu APC ipinlẹ Ọyọ lọdun 2018 to si dupo gomina lorukọ ẹgbẹ ọhun lasiko idibo gbogbogboo ọdun 2019, ṣugbọn ti Gomina Makinde la oun atawọn oludije yooku ninu idibo naa mọlẹ.
Ṣugbọn nnkan ko ṣenuure fun Pẹnkẹlẹmẹẹsi ninu idibo abẹle ẹgbẹ Onigbaalẹ ọtẹ yii pẹlu bi aṣofin agba to n ṣoju ẹkun idibo Aarin-Gbungbun ipinlẹ Ọyọ lọwọlọwọ, Sẹnetọ Tẹslim Fọlarin ṣe fagba han an ninu idibo ọhun to waye ni papa iṣere Ọbafẹmi Awolọwọ, laduugbo Oke-Ado, n’Ibadan, lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja.