Monisọla Saka
Ọdun Keresi to yẹ ko jẹ asiko idunnu ati ayọ fawọn eeyan agbegbe Obogoro, nijọba ibilẹ Yenagoan nipinlẹ Bayelsan ti yipada di ọjọ ibanujẹ, ẹkun ati oṣe bayii pẹlu bi ọkan ninu awọn ọdọ agbegbe naa, to tun ti figba kan jẹ oye olori awọn ọdọ adugbo naa ri, Ọgbẹni Sobokime Igodo, ṣe dagbere faye lẹyin ti maaluu ti wọn ra fun ọdun Keresi kan an pa.
Ori foonu ni wọn lọkunrin naa ti n sọrọ lọwọ laaarọ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kejila, ọdun yii, ti maaluu ti wọn fẹẹ pa ni apapin ki wọn le ri ohun fi ṣọdun fi lọọ kan an nibi to duro si, niṣe lo gbe e wọnlẹ, to si ṣẹ eegun ẹyin rẹ, t’ọkunrin naa si ṣe bẹẹ dagbere faye.
ALAROYE gbọ pe oloogbe yii atawọn ọrẹ ẹ ni wọn jọ dawo jọ ra odidi maaluu ti wọn maa pin laarin ara wọn gẹgẹ bii iṣe wọn lọdọọdun.
Ile oloogbe funra ẹ ni gbogbo wọn fẹnu ko le lori lati pa maaluu naa, ti wọn yoo si ti tun pin in nibẹ. Awọn alapata meji ti wọn pe lati waa ba wọn yanju ẹran ti wa nibẹ, wọn n wa ọna lati gbe ẹran naa dide ko le rọrun fun wọn lati da a dubulẹ, ki wọn si pa a, ṣugbọn maaluu naa kọ ko dide.
Akitiyan yii ni wọn n ṣe lọwọ ti Igodo fi jade sita lati wo ibi ti wọn ba iṣẹ de, ṣugbọn ọrọ to n sọ lori foonu ko jẹ ko ribi kiyesi wahala ti maaluu n fi awọn alapata naa ṣe. Lojiji ni maaluu dide wuya, to gbera sọ nibi to jokoo si, to si fori le ibi ti oloogbe ọhun duro si to ti n baayan sọrọ lori foonu, nigba ti tọhun ko si mọ pe nnkan kan n bọ, lẹẹkan naa ni maaluu kan ọkunrin naa gbau, ẹyin ti Igodo ba lọ silẹ bayii, gbalaja lo na silẹ, ti ko tilẹ le ri ara gbe nilẹ to wa, eyi ni wọn lo ṣokunfa bi ọpa ẹyin ẹ ṣe kan.
Ileewosan ijọba, Federal Medical Centre (FMC), to wa ni Yenagoa, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ naa, ni wọn sare gbe e digbadigba lọ, ko too di pe awọn tọhun tun dari wọn lọ si ileewosan ikọṣẹ iṣegun Fasiti ilu Portharcourt ( UPTH) fun iwosan to peye ni kiakia. Ọsibitu ilu Port Harcourt ti wọn dari wọn si yii lo ti pada dagbere.
Iku ọkunrin yii ni wọn lo ti da ibanujẹ silẹ ni agbegbe naa, ti ọjọ lasan gan-an fi san ju ọjọ ọdun lọ niluu ọhun gẹgẹ bi awọn eeyan ṣe n kari bọnu ṣọfọ iku oloogbe.
Ko sẹni to mọ boya wọn yoo si pa maaluu to ṣeku pa olowo rẹ yii, ati pe bi wọn ba pa a awọn eeyan yoo le jẹ abami maaluu naa.