Loni-in ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹtala oṣu keje, ọdun 2020, Ọgbẹni Ibrahim Magu ti i ṣe olori ileeṣẹ amunifọba ti n gbogun tiwa ibajẹ (EFCC) tẹlẹ, ti tun wa niwaju awọn ọmọ igbimọ ti wọn n fọrọ wa a lẹnu wo nile ijọba, Aso Rock, niluu Abuja. Ọjọ Mọnde ọsẹ to kọja lọkunrin naa ti bẹrẹ si i jẹjọ niwaju igbimọ yii, nibi ti wọn si fi ọrọ naa ti si lọsẹ to kọja ni wọn yoo ti tun gbe e. Ẹsun pe awọn owo kan sọnu mọ ọn lọwọ, o ko awọn mi-in jẹ, o tun ta dukia to gba lọwọ awọn akowojẹ nitakuta ni wọn n tori ẹ fọrọ gbe e lẹnu jo.
Awọn ẹsun oriṣiriṣi mi-in ni wọn tun fi kan Magu, lati igba ti wọn si ti fipa mu un lọsẹ to kọja lo ti n jejọ niwaju igbimọ naa ti Adajọ agba tẹlẹ nile ẹjọ Kotẹmilọrun, Ayọ Salami, jẹ alaga wọn. Ko ti i jọ pe awọn idahun Magu tẹ awọn ti wọn n wadii aṣemaṣe ti wọn lo ṣe yii lọrun ni ọrọ rẹ ṣe di ogun wa loni-in, wa lọla.
Lati ọjọ ti wọn ti mu un lo ti wa nitimọle, bo si tilẹ jẹ pe o ti kọwe si ọga ọlopaa pata pe ki iyẹn jẹ ki wọn gba beeli oun, ko ti i jọ pe wọn da a lohun, bo ba si ṣalaye ọrọ tan loni-in yii, o jọ pe itimọle naa ni yoo tun pada lọ. Titi ti a fi n kọ iroyin yii Magu ṣii wa nile ipade nla inu Aso Rock, nibi ti igbimọ to n gbọ ẹjọ rẹ yii ti n jokoo lojoojumọ.