Makinde ati ọrẹ ẹ gba idajọ iku, fila ti wọn gbagbe sibi ti wọn ti fipa baayan lo pọ lo tu wọn fo

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ile-ẹjọ giga kan nipinlẹ Ekiti ti paṣẹ pe ki wọn fi okun si ọrun ọmọdekunrin ẹni ọdun mejidinlogoji kan, Kọla Makinde, ati ọrẹ rẹ timọ-timọ, Bika Haruna, titi ẹmi yoo fi bọ lẹnu wọn.

Awọn ọrẹ meji yii ni wọn ko wa sile-ẹjọ lori ẹsun mẹfa, eyi to da lori igbimọ-pọ lati ṣiṣẹ ibi, idigunjale, ifipa ba ni lo pọ ati ijinigbe, ni Ilasa-Ekiti, nijọba ibilẹ Ikọle.

Makinde ni awọn ọlọpaa gbe wa siwaju ile-ẹjọ ti Onidaajọ Ọlalekan Ọlatawura n ṣe akoso rẹ, lọjọ kejidinlogun, oṣun Keji, ọdun 2022.

Gẹgẹ bi iwe ẹsun naa ṣe sọ, ni ọjọ kẹfa, oṣu Kẹwaa, ọdun 2021, Makinde ati Haruna digun ja Ọgbẹni Lawrence Oni ati Mohammed Ayomide lole ni agbegbe idi Mango, ni Ilasa-Ekiti, ti wọn si gba ẹrọ ilewọ wọn. Bakan naa ni won tun gba bii ẹgbẹrun lọna mọkanlelọgbọn Naira lọwọ wọn.

Lọjọ yii kan naa ni wọn tun ji ọmọdebinrin ẹni ọdun mọkandinlogun, Daramọla Adejuwọn, gbe lẹyin ti wọn fipa ba a lo pọ tan. Awọn ọdaran wọnyi tun fipa ba obinrin to n tọ ọmọ oṣun marun-un lọwọ lo pọ.

Ile-ẹjọ naa fikun un pe nigba ti wọn ṣe ẹsẹ yii, oun ija oloro bii ibọn ati ada pẹlu ogun oloro ni wọn ko dani, gbogbo ẹsẹ wọnyi ni ile-ẹjọ yii juwe gẹgẹ bii oun to lodi sofin.

Nigba ti awọn ọlọpaa n gba ohun wọn silẹ, awọn ti ọdaran wọnyi ṣe akọlu si sọ pe awọn ọdaran naa ni wọn fi agbara ṣilẹkun wọn, ti wọn si na ibọn si wọn, ti wọn bẹrẹ si i fi ada to wa lọwọ wọn na wọn titi ti wọn fi gba ẹrọ ilewọ ati gbogbo owo to wa lọwọ wọn.

Wọn fi kun un pe wọn fipa ba ọmọdebinrin kan, Adewumi Daramola lo pọ, ti wọn si tun ji i gbe lọ. Lẹyin ti wọn ji i gbe ni wọn beere miliọnu marun-un Naira gẹgẹ bii owo itusilẹ lọwọ awọn mọlẹbi rẹ.

Bakan naa ni wọn tun fipa ba obinrin kan to n tọ ọmọ oṣu marun-un lọwọ lo pọ. Obinrin yii ni ni kete ti wọn wọ inu yara oun, wọn gba ọmọ oun lọwọ oun, wọn si fipa ba oun lo pọ.

Ọwọ awọn fijilante to wa niluu naa pada tẹ awọn ọdaran ọhun, lẹyin ti wọn ri fila kan ti wọn gbagbe sibi ti wọn ti ṣe ọṣẹ naa.

Lati fi idi ẹjọ rẹ mulẹ, Agbefọba, Olasanmi Oluwaṣeun, pe ẹlẹrii meje, o si tun ko gbogbo iwe ti awọn ọlọpaa fi gba ọrọ silẹ lẹnu awọn ọdaran naa silẹ.

Bakan naa ni awọn ọdaran ọhun sọrọ lati ẹnu agbẹjọro wọn, Iyanu Olumuagun, ti wọn si pe ẹlẹrii kan pere.

Onidaajọ Ọlalekan Ọlatawura, ṣalaye pe pẹlu gbogbo ẹri to wa niwaju ile-ẹjọ naa, o fi han pe loootọ ni awọn ọdaran naa ṣẹ ẹṣẹ idigunjale ati ijinigbe.

O paṣe pe awọn ki wọn fokun si wọn lọrun titi ẹmi yoo fi bọ lẹnu wọn, bakan naa lo gba adura pe ki Ọlọrun fori ji oku wọn.

Leave a Reply